EKA ISE: EDE

AKOLE ISE: ATUYEWO AWON EYA ARA – IFO (EYA ARA ISORO)

Eya ara ifo ni eya ara ti a maa n lo fun gbigbe iro ifo jade

A le pin eya ara ifo si isori meji, awon ni;

  1. Eya ara ifo ti a le fi oju ri: apeere: ete oke, ete isale, eyin oke, e yin isale, evigi, aja enu, iwaju a lo n, aarin lion, eyin ahon, afase, ita gongongo, olele, aja-enu, kaa imu
  2. Eya ara ifo ti a ko le fi oju ri: Apeere; Edo-foro, komookun, eka-komookun, tan-an-na, inu gogongo, kaa ofun.

 

AWON EYA ARA TI A FI N PE IRO EDE

AFIPE: Afipe ni gbogbo eya ara ifo ti won kopa ninu pipe iro ede jede. A le pin awon afipe wonyi si meji; awon nii

  1. APIPE ASUNSI: Eyi ni afipe ti o le gbera nigba ti a aba n pe iro won maa n sun soke sodo ti aban soro. Apeere; Afipe asunsi ni, Ete Isale, Eju isale, iwaju alion, aarin alion, eyin ahon, olele.
  2. AFIPE AKANMOLE: Eyi ni awon afipe ti ko le gbara soke sugbon ti won maa n duro gbari bi a ba n pe iro jade. Apeere afipe akonmole ni, ete oke, aja-enu, afase, iganna ofun, eyin oke, erigi, olele.

Ipo ti ahon ati ete wa ninu pipe faweli ede Yoruba

  1. IPO AHON: Nigba ti a ba pe iro faweli, ape kan ara ahon maa n gbe soke ti yoo su ike ninu enu

A le pin ahon si isori meta ninu pipe iro jade. Awon ni;

  1. Faweli waju: Eyi ni faweli ti a pe nigba ti iwaju ahon gbe soke ju lo ninu enu awon faweli naa ni,I,e,e,in,en.
  2. Faweli aarin: Eyi ni faweli ti a pe nigba ti aarin gbe soke ju lo ninu enu. Awon ni, a, en.
  • Faweli eyin: Faweli eyin ni faweli ti a pe nigba tie yin ahon gbe soke ju lo ninu enu, awon faweli naa ni, u, o,o,un,on.
  1. IPO ETE: Ipo meji ni ete le wa bi a ba n pe iro faweli. Ete le te perese tabi ki o su roboto.

Faweli perese: Eyi ni faweli ti a gbe jade nigba ti ete fe seyin ti alafo gigun tin-in-rin wa laarin ete memeeji.  Awon faweli naa ni, a,e,e,I,an,en,in.

Faweli roboto: Eyi ni awon faweli ti a gba jade nigba ti ete ka roboto. Awon ni, o,u,o,un,on.

 

EKA ISE: ASA

AKOLE ISE: EKO ILE- ASA IKINI

Eko ile ni eko iwa hihu: iwa rere, iwa to to, iwa to ye ti obi fi n ko omo lati kekere.

Eko ile je iwa omoluabi, ati kekere ni iru eko yii ti n bere ti yoo si di baraku fun omo titi ojo aye re.

Dandan ni fun omo lati mo bi ati n ki baba, iya ati awon miran ti o ju ni lo ni gbogbo igba.

 

Ikini akoko / igba.

  IGBA / AKOKO IKINI
I Ojo Eku  ojo / otutu
Ii Oye Eku oye
Iii Iyan Eku aheje kiri o
Iv Ni owuro Ekaa oro
V Ni osan Ekaa san
Vi Ni irole Eeku irole
Vii Ni oru Ekuaajin

 

Ikini akoko Ise

  ISE IKINI IDAHUN
I Agbe Aroko bodu de o Ase
Ii Onidiri Oju gbooro, eku ewa Iyemoja
Iii Babalawo Aboru boye, sboye bo sise Amin
Iv Awako Oko a re foo, goun a pana mo o Amin o
V Akope Igba a ro o O o
Vi Osise ijoba Oko oba ko ni sa yin lese Ase
Viii Iya oloja Aje a wo gba o Ase

 

EKA ISE: LITIRESO

AKOLE ISE: ATUYEWO ORISIRISI EYA LITIRESO

Litireso ni akojopo ti a fi oro ni ede kan tabi ti e ko sile.

Isori litireso

  1. Litireso alohun (atenudenu)
  2. Litireso apileko (alakosile)

Litireso alohun: Eyi  ni awon ewi ti a jogun lati enu awonn babanla wa.

Ohun enu ni a fi n gbe litireso jade, ko si ni akosile rara.

Litireso alohun kun fun o gbon imo ati oye agba, nigba ti imo moo ko moo-ke ko ti de ile wa ohun ni awon baba nla wa n lo ninu igbo ke gbodo won.

 

 

Litireso alohun pin si ona meta

  1. ewi
  2. oro geere
  3. ere onise.

Litireso apileko : Eyi ni litireso ti a se akosile nigba ti imo mooko-mooka de ile wa.

Litireso yin je litireso alakosile.

Litireso alohun ni ategun tabi orison litireso apileko

Isori litireso apileko ni wonyi,

a.ewi

  1. Ese-onitan
  2. itan aroso.

Igbelewon:

  • Fun eya ara ifo loriki
  • Pin eya ifo si isori
  • Salaye awon eya ara ti a fi n pe iro
  • Kin ni litireso?
  • Salaye isori litireso
  • Fun eko ile loriki

Ise asetilewa: bawo ni a se n ki awon wonyi ni ile Yoruba:

  1. Oba
  2. Ontayo
  • Alaboyun
  1. Ijoye ilu
  2. Iya olomo tuntun
  3. Akope

 

See also

Didaruko Faweli

OSE KESAN-AN

AKORI EKO: ITESIWAJU AWON ORISA ILE YORUBA

AKORI EKO: ITESIWAJU ONKA YORUBA

AKORI EKO: ORISA ILE YORUBA

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Get Fully Funded Scholarships

Free Visa, Free Scholarship Abroad

           Click Here to Apply

Acadlly