Iro-Ede -; ni ege ti o kere julo ti a le fi eti gbo ninu ede, ti a ba n ba eniyan soro ,iro ifo ni ohun ti eni naa yoo maa gbo.
Table of Contents
A le ko iro –ede sile nipa lilo leta tabi ami.Iro-ede ti a ni pin si ona meta;
Iro faweli
Iro ohun.
Iro Faweli:- ni iro ti a pe nigba ti ko si idiwo fun eemi ti o n ti inu edofooro bo.
Ona meji ni iro faweli pin si
Faweli Airanmupe.
Faweli Aranmupe.
Faweli Airanmupe je meje. Awon naa ni a, e, e, i, o, o, u.
Faweli aranmupe je marun-un. Awon naa ni: an, en, en, in, un.
ADAKO IRO FAWELI
Ilana Akoto Ilana Fonetiiki
a [ a ]
e [ e ]
e [ Ɛ ]
I [ i ]
o [ o ]
o [ Ɔ ]
u [ u ]
an [ a ]
en [ Ɛ ]
in [ i ]
on [ Ɔ ]
un [ u ]
ABUDA FUN ISAPEJUWE IRO FAWELI: Eyi ni abuda ti a n lo fun isapejuwe iro faweli.
- Ipo ti Ahon wa.
- Ipo ti Ete wa.
- Ipo ti Afase wa.
- Ipo ti Apa to gbe soke ga de ninu enu.
IPO TI AHON WA-; bi a ba tele abuda yii,ona meta ni a le pin iro faweli si,nitori pe ona meta ni ahon wa pin si,ipo ahon kookan lo si ni iro faweli ti a fi n pe.
Faweli iwaju
Faweli aarin.
Faweli eyin
Faweli Iwaju– eyi ni faweli ti a fi iwaju ahon pe,ap I,e,e
Faweli Aarin– eyi ni faweli ti a fi aarin ahon pe.ap “a”
Faweli Eyin– eyi ni faweli ti a fi eyin ahon pe .ap o,u ,o.
IPO TI ETE WA-; bi a ba tele abuda yii, ona meji ni a le pin iro faweli si
Faweli roboto.
Faweli perese.
Faweli Roboto– eyi ni iro ti a pe nigba ti ete se roboto.ap u,o,o
Faweli Perese– eyi ni iro ti a pe nigba ti ete wa se perese.ap i,e,
IPO TI AFASE WA-; bi a ba tele abuda yii,ona meji ni a le pin iro faweli si
Faweli airanmupe
Faweli aranmupe
Faweli Airanmupe-; ni iro faweli ti a pe nigba ti afase gbe soke lati di kaa imu ,ti eemi si gba kaa enu jade. Ap: a, e, e, i, o, o, u.
Faweli Aranmupe-; eyi ni iro faweli ti a pe nigba ti afase wa sile lati di kaa enu ti eemi si gba kaa imu jade.Ap: an, en in, un.
IPO TI APA TO GBE SOKE JULO GA DE NINU ENU-; bi a ba tele abuda yii, ona merin ni a le pin iro faweli si:
Faweli ahanupe
Faweli ahanudiepe
Faweli ayanudiepe
Faweli ayanupe
Faweli Ahanupe (oke)-: ni faweli ti a pe nigba ti apa kan lara ahon ba gbe soke ti o si fere ga de aja-enu. Ap / I /, / u /, / in /, / un /.
Faweli Ahanudiepe (ebake)-: ni faweli ti a pe nigba ti apa kan to gbe soke ni ara ahon de ebake ,ti a ha enu die pee. Ap / e /, / o /.
Faweli ayanudiepe (ebado)-: ni faweli ti a pe nigba ti apa kan gbe soke to de ebado. Ap / Ɛ /, / Ɔ /, / Ɔ /, / Ɛ /.
Faweli ayanupe (odo)-;ni faweli ti a penigba ti apa kan gbe soke ni ara ahon wa ni odo. Ap / a /, / a /
ATE FAWELI AIRANMUPE
Ate yii ni o n so ipo tabi irisi ahon ni enu ti a ba n gbe iro faweli jade.
ATE FAWELI ARANMUPE
ISAPEJUWE IRO FAWELI
AIRANMUPE
[a]- aarin, airanmupe, ayanupe, perese.
[e]- iwaju, airanmupe, ahanudiepe, perese
[Ɛ ]- iwaju, airanmupe, ayanudiepe, perese.
[i ]- iwaju, airanmupe, ahanupe, perese.
[o]- eyin, airanmupe, ahanudiepe, roboto.
[ Ɔ ]- eyin, airanmupe, ayanudiepe, roboto.
[u]- eyin, airanmupe, ahanupe, roboto.
ARANMUPE
[ a ]- aarin, aranmupe, ayanupe, perese.
[ Ɛ ]- iwaju, aranmupe, ayanudiepe, perese.
[ i ]- iwaju, aranmupe, ahanupe, perese.
[ Ɔ ]- eyin, aranmupe, ayanudiepe, roboto.
[ u ]- eyin, aranmupe, ahanupe, roboto.
Akiyesi pataki: ki a ranti pe gbogbo iro faweli (aranmupe ati airanmupe) ni won je iro akunyun.
IWE ITOKASI:
Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.1 Corpromutt Publisher Nig Ltd. o.i 14-17.
IGBELEWON
- Se apejuwe iro faweli airanmupe pelu ate.
- Se apejuwe iro faweli aranmupe pelu ate.
IGBAGBO ATI ERO YORUBA NIPA OSO ATI AJE
Akoonu
Awon Yoruba gba pe oso ati aje wa, won tile ni igbagbo yii to bee ti o fi je pe o soro lati ri eni ti o ku, yagan tabi ti wahala sele si ti won ko ni so o mo oso ati aje.
Bakan naa awon Yoruba gbagbo pe oso ati aje ni agbara oogun ti won le fi pa eni ti won ba fe. Ewe won gbagbo pe inu ipade aje ni won ti maa n duna- an- dura bi won yoo se pa eni ti won ba fe pa. Won gbagbo pe ona meji ni okunrin fi n gba oso
-ajogunba
-wiwo egbe oso
bee naa ni ti aje o le je nipa ajogunba
Iyato laarin oso ati aye. Iyato to wa laarin oso ati aje ni pe awon okunrin lo maa n je oso ni gba ti awon aje je obinrin.
IGBELEWON
- Salaye lori igbagbo awon Yoruba nipa oso ati aje.
- Ko iyato kan ti o wa laaarin oso ati aje
LITIRESO
KIKA IWE APILEKO TI IJOBA YAN ( EWI IGBALODE) ‘Taiwo Olunlade. NECO
APAPO IGBELEWON
- Se apejuwe iro faweli airanmupe pelu ate.
- Se apejuwe iro faweli aranmupe pelu ate.
- Salaye lori igbagbo awon Yoruba nipa oso ati aje.
- Ko iyato kan ti o wa laaarin oso ati aje
- ISE SETILEWA
- Iro iwaju ni (A) a (B) e (C) u (D) o
- Iro airanmupe ni iro (A) a (B) an (C) o (D) u.
- Faweli ahanupe iwaju ni (A) a (B) e (C) c (D) i.
- Faweli roboto ni (A) i (B) e (C) a (D) o.
- Ewo ni ko si lara ise ti awon aje maa n se? (A) iwosan (B) itusile (C) ounje fifun ni (D) pipani
APA KEJI
- Ya ate faweli airanmupe pelu alaye.
- Ya ate faweli aranmupe pelu alaye.
See also