IRO KONSONANTI

Iro konsonanti-; ni iro ti a pe nigba ti idiwo wa fun eemi ti o n ti inu edofooro bo.iro konsonanti mejidinlogun lo wa ninu ede Yoruba. Awon naa ni; b,d, f, g, gb, h, j, k, l, m, n, p, r, s, s, t, w, y.

APEJUWE IRO KONSONANTI

AKOONU

Iro Konsonanti: ni iro ti a pe nigba ti idiwo wa fun eemi ti o ti inu edofooro bo. Iro konsonanti mejidinlogun lo wa ninu ede Yoruba awon naa ni: b, d, f, g, gb, h, j, k, l, m, n, p, r, s, S, t, w, y.

 

ABUDA FUN ISAPEJUWE IRO KONSONANTI

Eyi ni awon abuda ti a maa tele ti a ba fe sapejuwe iro konsonanti:

Ipo ti alafo tan-an-na wa.

Ipo ti afase wa.

Ibi isenupe.

Ona isenupe.

 

IPO TI ALAFO TAN-AN-NA WA

Bi a ba tele abuda yii, ona meji ni a le pin iro konsonanti si

Konsonanti aikunyun.

Konsonanti akunyun.

Konsonanti Aikunyun-: ni iro ti a pe nigba ti alafo tan-an-na fi aye ti o to sile fun eemi ti o n ti inu edofooro bo,eyi ni pe  ko si idiwo. Apeere konsonanti aikunyun ni t, k, p, f, s, s, h.

Konsonanti Akunyun-: ni a pe nigba ti alafo tan-an-na sunmo ara won pekipeki,ti idiwo si wa fun eemi  ti n ti inu edofooro bo. Ap /b/, /d/, /g/, /l/ abbl

 

IPO TI AFASE WA

Bi a ba tele abuda yii, ona meji ni a le pin iro faweli si,awon naa ni

Konsonanti airanmupe

Konsonanti aranmupe

 

Konsonanti Airanmupe-: ni iro ti a pe nigba ti afase gbe soke lati kaa imu, ti eemi si gba kaa- enu jade. ap/b/, /d/, /f//, /k/, /l/.

 

Konsonanti Aranmupe-: ni iro konsonanti ti a pe nigba ti afase wa sile lati di kaa-enu ti eemi si gba kaa-imu jade. ap /m/,/n/.

IBI ISENUPE

Ibi isenupe-: eyi ni o n tokasi afipe asunsi ati akanmole ti a lo lati gbe iro konsonanti jade.

Ibi isenupe pin si ona mejo

Afeji-ete-pe

Afeyin-fetepe

Aferigipe

Afaja-ferigipe

Afajape

Afafasepe

Afafase-fetepe

Afitan-an na-pe

 

ONA ISENUPE

Ona Isenupe-: ni o n tokasi iru idiwo ti o wa fun eemi ni gbigbe awon iro konsonanti jade. Ona meje ni ona isenupe pin si, awon naa ni

Asenupe

Afunnupe

Aranmu

Arehon

Afegbe-enu-pe

Aseesetan.

Asesi.

 

IGBELEWON

Kin ni iro konsonanti?

Daruko awon abuda fun isapejuwe iro konsonanti.

 

IWE ITOKASI:

Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.1 Corpromutt Publisher Nig Ltd. o.i 14-17.

 

Bi a ti n sin oku oba yato patapata si bi a ti n sin oku eniyan lasan.Awon oba alade po ni ile Yoruba,bi a si ti n sinku oba ni ilu kan yato si ti ikeji, ati pe ipo oba kan yato si ara won. Isinku Alaafin ni a o fi se apeere.

Ilu ati ibon yiyin ni  a fi n tufo oba ati arugbo,won ki i tete tufo oku oba, ki awon omo to fi to awon oloye leti ni won yoo to palemo gbogbo ohun ti o ba je ohun ini ti oba ni won yoo ti palemo.

Leyin eyi ni awon omo oba yoo lo so fun awon ijoye pe ara baba awon ko ya, nitori pe won ko ni ase lati so fun won pe oba waja.Nigba ti awon ijoye ba de aafin ni won yoo to mo pe oba ti gbe emi mi, a ki i so pe oba ku, nitori pe oba ki i ku,oba wo aja-ile.A tun le so pe erin wo,opo ye tabi ile baje.

Gbara ti oba ba ku,ni awon ijoye ati awon agbaagba ti ise tabi ipo oye won ba je mo isinku oba, yoo ti bere etutu ati oro –isinku oba nitori pe aki i sinku oba gege bi a ti i sinku eniyan lasan.Oku gbogbo ilu ni oku oba,ni Oyo ilu koso ati fere Okinkin ti a fi eyin gbe.

Ni Bara ni won maa n sin oku Alaafin si ni aye atijo,lale si ni won maa n se eto oku naa,opolopo etutu ni won o ti se.

Ona-Onse Awo ni oloye ti ipo oye re jemo isinku oba Alaafin.Oloye yii ni yoo ge ori oba to waja,inu yara kan to wa laafin, ti a n pe ni ile ori ni yoo gbe ori oba si fun ilo oba ti yoo tun je tele e.

Bi won ba fe lo sin oku oba to ku ni Bara, won a fon fere Okinkin,a o si lu ilu koso lati so fun awon ara ilu  pe oba n re ile igbeyin lati lo sun.

Ibi mokanla ni awon oloye to gbe oba yoo ti duro ki won to de Bara nitori pe ibe jinna die si aarin ilu.Nibi kookan ti won ba ti duro si ni won yoo ti fi eeyan kan ati agbo kan rubo.

Koto ti a o sin oku Alaafin si maa n fe pupo,yoo gun daadaa,bee ni yoo si jin gidi nitori opolopo nnkan ti a o sin pelu re,aso dudu ati aso funfun ni a fi n sinku oba Alaafin.

Bi won se n sinku oba ni pe won a te oku oba si aarin koto ti a gbe,leyin eyi won a pa obinrin mejo,won a te merin si igberi re ati merin si igbase re .won a tun pa awon giripa okunrin merin,won o te meji si egbe re otun ati osi,leyin eyi ni won yoo wa ko oku awon mokanla ti a fi rubo loju ona,ki a to de Bara sinu koto nla naa.

Awon metalelogun ti a sin pelu oba ni won gbagbo pe yoo maa se iranse fun oba lona orun ati ni orun nibi ti o n lo.

Igbagbo won ni pe ipo ti oba wa laye ni yoo wa ni orun,nitori naa oba  ni lati ni opolopo obinrin  ati iranse.leyin gbogbo re ni won yoo pa eni ti o gbe ina lowo ti a fi se gbogbo eto isinku yii,won yoo gbe oku re pelu awon iranse ti o wa ninu koto.

Awon iyawo,omo,ore,ati ebi yoo wa bere si ko ebun,ounje ti won ko way ii ni won lero pe yoo wulo fun oba lona irin-ajo ti o n lo.leyin gbogbo eyi ni won yoo wa ro eepe bo gbogbo ohun ti o wa ninu koto.

Ayipada ti de ba bi a ti n sin oku oba laye ode-oni,won ko fi eniyan se etutu mo ni ilu oyo esin ati maluu ni won n lo bayii.

 

 

Akudaaya ni awon ti won ku ti won tun wa fi ara han ni ibomiran. Igbagbo Yoruba ni wi pe iru awon eniyan bayi ko i lo iye odun ti won ye ki won lo laye ki won to ku. Iku won le je sababi nnkan kan. Awon eda bee yoo lo si ilu miiran lati lo lo odun ti o ku nibe. Akudaaya le ni ni iyawo tabi ni oko ni ilu miiran ti o lo.

 

IGBELEWON

  1. Ki ni igbagbo awon Yoruba nipa akudaaya?
  2. Ko apeere abami eda marun-un sile.

 

LITIRESO

KIKA IWE APILEKO TI IJOBA YAN ( EWI IGBALODE) ‘Taiwo Olunlade. NECO

 

APAPO IGBELEWON

  1. Kin ni iro konsonanti?
  2. Daruko awon abuda fun isapejuwe iro konsonanti
  3. Ki ni igbagbo awon Yoruba nipa akudaaya?
  4. Ko apeere abami eda marun-un sile.

 

ISE ASETILEWA

  1. Iro ti idiwo wa fun eemi re ni iro (A) konsonanti (B) faweli (C) ami (D) iro.
  2. Ewo ni iro akunyun? (A) f (B) h (C) gb (D) t
  3. Ewo ninu iro konsonanti yii ni eemi se mo patapata? (A) f (B) s (C) h (D) x
  4. As1nup4 ni (A) l (B) d (C) g (D) m
  5. Zk5dzqyz ni cni t7 9 fi 8l5 kan s7l2 l[ s7 8l5 m87rzn lqtzr7 p3 9 ……… (A) ku (B) salo (C) je gbese (D) binu.

APA KEJI

  1. Salaye awon iro konsanati yii ni kikun: k, gb, r, y, w
  2. Awon wo ni a n pe ni abami eda? Salaye pelu apeere.

 

See also

IRO FAWELI

EYA ARA IFO

ORUNMILA

AWON ORISA ILE YORUBA

ORO-ORUKO NI ILANA APETUNPE

Acadlly Playstore Brand logo 350 x 350