AWON ORISA ILE YORUBA

Ona meji pataki ni a le pin awon orisa ile Yoruba si.  Awon orisa kan wa to je pe won ro wa lati orun,  orisa ni Olorun da won, won ki i se eniyan nigba kan kan ri. Awon orisa ipin keji ni awon eniyan ti a so di orisa nitori ise  ribiribi owo won nigba ti won wa laye.  Awon wonyi ki i se orisa lati orun wa.  Apeere awon orisa ti won ro wa lati orun ni Obatala, Orumila, Ogun, Esu. Awon ti a so di orisa akunlebo ni yemoja, sango, oya, osun, oba, meremi, orisa oko ati bee bee lo.

 

OGUN( god of iron):  Ode ni Ogun ni aye atijo. Tabutu ni oruko iya ogun.Oririnna si ni baba re O je oye Osinmole ni ile Ife, ki o to lo si ilu ire Ekiti. Mariwo ni aso Ogun, eje lo si maa n mu. Gbogbo ohun to je mo irin je ti ogun Ogun korira ki won gbe koronfo agbe emu duro. O tun korira iwa eke, iro pipa, ole jija

 

A gbo nigba ti awon orisa n ti ikole orun bow a si ile aye, won se alabapade igbo didi kijikiji kan. Orisa-Nla ni a gbo pe o koko lo ada owo re lati la ona yii sugbon ada fadaka owo re se. Ogun ni a gbo wi pe o fi ada irin  owo re la ona gberegede fun awon orisa yooku lati koja. Ise ribiribi ti ogun se yii ni awon orisa yii se fi je oye Osin-Imole ni Ile Ife. Itan yii fi han pe ode ti o ni okiki ni ogun.

 

IGBAGBO YORUBA NIPA OGUN

  1. Ogun ni orisa ti o ni irin.
  2. Oun ni o la ona fun awon orisa elegbe re.
  3. O je orisa ti o feran ododo ati otito.
  4. Orisa ogun ni Ogun
  5. Gbenagbena ni Ogun.

 

AWON OHUN TI WON FI N BO OGUN

Aja, esun isu, epo, adiye, agbo, ewure, eyele, igbin, ewa, eyan, iyan, obi abata, orogbo, ataare ati emu. Eekan soso ni apaja ogun gbodo be aja ogun ni orun ti won ba n boo gun.

 

BI WON SE N BO OGUN

Bi won se n bo Ogun ilu naa ni won n bo Ogun idile kookan. okuta ribiti lo duro fun ogun agbede. Ori re ni awon alagbede ti n ro oko ati ada.

 

ORIKI OGUN

Ogun lakaaye Osin Imole

Ogun alada meji

O fi okan san’ko

O fi okan ye’na

Ojo ogun n ti ori oke bo

Aso ina lo mu bora

Ewu eje lo wo

Ogun onile owo

Ogun onile owo, olona ola

Ogun onile kangunkangun orun

O pon omi sile f’eje we

Ogun meje logun mi

Ogun alara ni gb’aja

Ogun Onire a gb’agbo

Ogun Ikola a gba’gbin ……

 

ORISA-NLA/OBATALA

Orisa-Nla ni asaaju gbogbo awon orisa. Oun ni won gbagbo pe o je igbakeji Olodumare, nitori oun ni Eledaa koko da. Oun naa ni a tun n ni Obatala, iyen ‘Oba ti ala’

 

IGBAGBO YORUBA NIPA ORISA-NLA

  1. Alamo ti o mo ori.
  2. Orisa funfun ni
  3. Asaaju awon Orisa to ku ni.

 

OUNJE TI WON FI N BO ORISA-NLA

  1. Iyan ati obe eran igbin t won fi ori se.
  2. Omi idaji ni o maa n mu.

 

ORIKI

Alase, O so enikan soso di igba eniyan

Somi di’run, somi di’gbea

Somi d’otale-legbee eniyan

Orisa eti eni ola

O fi ojo gbogbo t’obi

O t’obi lai-segbe

Banta banta ninu olao sun ninu ala

O ji ninu ala

O ti inuala dide

Baba nla, oko Yemowo!

 

ESU

Esu je orisa pataki nile Yoruba. Oun ni o je olopaa si Olodumare. Oun ni o si eto lati fi iya je eni ti o ba rufin. Esu korira omi gbigbona ati adi. O je orisa ti o maa n se ire ti o si maaa n se ibi. Babalawo ki i fi oro se ere.

 

BI WON SE N BO ESU.

Won maa n fi epo, eje aja tabi ti ewure bo esu. Ti won ba fe ki o se ibi ni won maa n fi omi gbigbna ati adi bo o.

 

IGBELEWON.

  1. Ki ni igbagbo Yoruba nipa orisa ogun?
  2. Ki ni igbagbo Yoruba nipa orisa Obatala?
  3. Ki ni igbagbo Yoruba nipa orisa esu?
  4. Ki oriki ogun

 

IWE ITOKASI:

Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.2 Corpromutt Publisher Nig Ltd. o.i 176-182.

KIKA IWE LITIRESO APILEKO

APAPO IGBELEWON

  1. Ko onka awon figo yii; 30,000, 35,000, 36,000, 47,000, 52,000.
  2. Ki ni igbagbo Yoruba nipa orisa ogun?
  3. Ki ni igbagbo Yoruba nipa orisa Obatala?
  4. Ki ni igbagbo Yoruba nipa orisa esu?
  5. Ki oriki ogun.

 

ISE ASETILEWA

  1. 20,000 ni (A) oke kan (B) oke meji (C) oke ogun (D) egberungun.
  2. 40,000 ni (A) oke meji (B) oke meta (C) okemerin (D) egberunji.
  3. …. ni orisa ti o ni agbara lori irin. (A) esu (B) ogun (C) obatala (D) orisa-nla.
  4. Esin ti o korira omi gbigbona ati adi ni (A) ogun (B) sango (C) obatala (D) esu.
  5. Orisa ti o maa nfi mariwo bora bi aso ni (A) ogun (B) sango (C) obatala (D) esu.

 

APA KEJI

  1. Ko onka yii: 30,000, 70,000, 500,000
  2. Ki oriki esu
  3. Ki orikii ogun
  4. Ki oriki obatala.

 

See also

ORO-ORUKO NI ILANA APETUNPE

ISEDA ORO-ORUKO

AYOKA ONISOROGBESI

ORI-ORO | SILEBU EDE YORUBA

AROKO AJEMO ISIPAYA

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Get Fully Funded Scholarships

Free Visa, Free Scholarship Abroad

           Click Here to Apply

Acadlly