ORUNMILA

Orunmila ni alakoso ifa. O si je okan pataki ninu awon orisa ile Yoruba. Oke Igeti ni Orunmila koko duro si ki o lo si oke *tas2. O lo opolopo odun ni Ife Ondaye ki o to lo si Ado. Ibi ti o tip e julo ni ode aye. Idi niyi ti won fi n so pe ‘Ado n’ile Ifa’ Orunmila tun gbe ni Otu Ife. Ibe ni o ti bi awon omo wonyi: Alara, Ajero, Owarangun-aga, Oloyemoyin, Ontagi-Olele, Elejelu-mope ati Olowo. O tun gbe ni Ode Oyan. Ibi ti o ti bi Amukanlode-Oyan. Bakan naa ni o gbe ni ode Onko ti o ti bi Amosunlonkoegi.

 

IGBAGBO AWON YORUBA NIPA ORUNMILA

  1. Orunmila alakoso, ogbo, Imo ati Oye.
  2. Opitan ni Orunnmila.
  3. Okunrin kukuru dudu ni Orunmila
  4. Orunmila ni alakoso Ifa dida ati ale
  5. Orunmila ko ni egungun lara lati sise agbara.
  6. Agbaye-gborun ni Orunmila.

 

BI WON SE N BO ORUNMILA

Ojo awo ni won n bo Orunmila bi o tile je wi pe ojoojumo ni awon babalawo no Ifa. Bi won se n difa oroorun naa ni won n se odun Ifa ni odoodun.

 

Ti won ba fe bo ifa ni owuro, babalawo yoo mu obi sinu omi tutu, yoo maa fi iroke lu opon ifa, yoo maa ki Orunmilani mesan-an-mewaa. Babalawo yoo pa obi naa, yoo se oju obi si inu omi. Omi naa ni yoo lo da fun esu. Babalawo yoo lo da obi naa lati mo bi ifa ba gba a. bi obi bay an tako-tabo, iyen ti oju meji si oju, ti meji da oju deile. Ifa ti gba obi nu un. Babala yoo pin obi naa fun awon to wa niba lati je.

 

Bi o ba je ifa odun, awon nnkan repete ni won yoo ka sile. won yoo sip e mutumuwa fun ariya.

 

IGBELEWON

Salaye igbagbo awon yoruba lori Orunmila

 

IWE ITOKASI:

Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.2 Corpromutt Publisher Nig Ltd. o.i 164-166.

 

SANGO

Eniyan ni a gbo pe Sango je ki o to di orisa. Sango je orisa ti ise, irisi ati isoro re kun fun iberu. Sango je omo Oranmiyan. Awon iyawo re ni Oya, Osun ati Oba. Itan so fun  w a pe o je oba ni ilu Oyo. O ni agbara o si ni oogun. Ti inu ba n bi Sango, ina maa n yo ni enu re. Ninu itan kan, Sango si agbara lo o si pokunso lori igi aayan. Bayi ni awon iyawon re meteeta se parade di alagbalugbu omi. Oya wole ni Ira. Titi di oni ni won n boa won meteeta.

 

IGBAGBO YORUBA NIPA SANGO

  1. Orisa ti o ni agbara lori ara ati monamona ni.
  2. O je orisa afajo.
  3. O n fun won lomo.

 

OHUN TI WON FI N BO SANGO

Orogbo ni obi Sango. Won n fi oka, adiye ati aguntan bolojo bo o. Ounje Sango ni oka.

 

ORIKI SANGO

Penpe bi asa, asode bi ologbo

Sangiri-lagiri

Olagiri kaka f’gba edun bo o!

Eefin ina la n da laye

Ina n be lodo oko mi orun.

Sango onibon orun

Ajalaji Oba koso

 

IGBELEWON

Salaye lori esin Sango.

 

IWE ITOKASI:

Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.2 Corpromutt Publisher Nig Ltd. o.i 173-175.

 

APAPO IGBELEWON

  1. K o onka yii: 70,000, 90,000.
  2. Salaye lori esin Orunmila.
  3. Ki ni igbagbo Yoruba lori Sango.

 

LITIRESO

Ewi Igbalode: Taiwo Olunlade. (NECO).

 

ISE ASETILEWA

  1. Esin ti o ni agbara lori ina ni (A) ogun (B) sango (C) orunmila (D) esu. (A) (B) (C) (D)
  2. Esin ti o ni agbara lori ara ni (A) ogun (B) sango (C) orunmila (D) esu.
  3. Esin ti awon Yoruba gbagbo pe o asaaju awon orisa yoku ni (A) ogun (B) sango (C) orunmila (D) esu.
  4. Esin ti o maa n lo iroke ni (A) ogun (B) sango (C) orunmila (D) esu.
  5. Orisa ti o mo ori ni (A) ogun (B) sango (C) orunmila (D) esu.

 

APA KEJI

  1. Ki oriki Orunmila
  2. Ki oriki Sango.

 

See also

AWON ORISA ILE YORUBA

ORO-ORUKO NI ILANA APETUNPE

ISEDA ORO-ORUKO

AYOKA ONISOROGBESI

ORI-ORO | SILEBU EDE YORUBA

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Get Fully Funded Scholarships

Free Visa, Free Scholarship Abroad

           Click Here to Apply

Acadlly