AYOKA ONISOROGBESI

Ka ayoka isale yii,ki o si dahun ibeere ti o tele e

Ayo;               O da a,aanu re lo se mi

O mo on so, o dun lete re bi oyin

N o gba o si  egbe wa.

Baba Ramo     Haa! E seun o. Mo dupe o.

Ayo                 Sugbon owo iwegbe re n ko-

Poun  meedogun

Baba Ramo      Howu! Mo te patapata nu-un

Onini sagba mi lonii…….. sugbon mo be yin e gba mi.

Ayo                   Oro re ti e tu mi lara.

N o saanu re, a o gbowo fun o

Sugbon baa ba ti gbowo fun o.

Niwo naa o yara gbe nnkan fun wa

O domo egbe nu-un.

Baba Ramo       Ki le fe ki n gbe fun yin?

Ki le wi pe ki n gbe wa ti n ko nii gbe wa?

Ayo                   Apo marun-un la o gbe fun o.

Baba Ramo        Haaa ! kin ni n toju wa?

Ayo                    A o ni igbowo ohun fun o nisinsinyi

O digba too ba mu nnkan ta a wi wa.

Baba Ramo         Ko buru. Kin ni n toju wa?

Ayo                     Kii se nnkan pataki

Sugbon ,ohun ti o le won die ni

O o dolowo, o o tun tosi mo laelae

Bo o ba le fun wa ni wundia ti ko tii wole oko.

Baba Ramo         Ha !Eni to bimo nii romo gbe jo

Eniyan ti o bimo, ko le ri gbe pon

Bi o somo langidi?

N o bimo ! Tabi n o ti se e bayii?

Ayo                      Tulaasi ko

Ko sitiju; ko sowo

Bowo o ba te wundia ti o ti i rele oko.

Baba Ramo          Wundia? Haa  Hun-un

Gbogbo ara ile-yin nko?,nibo ni won lo?

Owo olowo,owo eni

Kedumare  o ma jee ka fe kan ku l’apo wa.

 

IGBELEWON

 1. Nnkan ninu ayoka yii n toka si?
 2. Kin ni baba Ramo wa de inu egbe yii?
 3. Kin ni idi ti baba Ramo fi so pe oun te?
 4. Kin ni yoo sele ti baba Ramo ba ri ohun ti won ni ko mu wa wa?
 5. Eelo ni Ayo seleri lati fun baba Ramo?
 6. Kin ni Ayo n reti lati odo baba Ramo?
 7. Nigba ti Ayo beere nnkan lodo baba Ramo kin ni o so?
 8. Salaye idi ope baba Ramo ninu ayoka yii.

 

IWE ITOKASI

Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.2 Corpromutt Publisher Nig Ltd. O.I 58-62.

 

ONA IBANISORO AYE ATIJO

Ibanisoro ni ona ti eniyan meji tabi ju bee lo n gba fi ero inu won han si ara lona ti o fi ye won yekyeke. Ona yii ni a n pe ni ede. Ede ni o n fun ohun ti a n so ni itumo. Awon ona ti a n gba ba ara eni soro ni

 1. Lilo Eya Ara fun Ibanisoro: oju, ori, imu, enu, ejika, ese, eekanna, owo, ete.
 2. Iparoko: (i) ilu lilu (ii) edan ogboni (iii) opa ase, (iv) owo eyo (v) awo edan (vi) irukere (vii) sigidi (viii)iye adie (ix) ebiti ati awo ehoro (x) owo-eyo meta (xi) aso ibora (xii) igbale (xiii) eepo igi ose ati aso pupa (xiv) idaji agbe emu tabi ajadi agbon.

 

IGBELEWON

Salaye ona mewaa ti awon Yoruba n gba ba ara won soro.

 

IWE ITOKASI:

Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.2 Corpromutt Publisher Nig Ltd. O.I 58-62.

 

ATUPALE IWE ASAYAN

Atupale iwe asayan ti ijoba yan.

 

APAPO IGBELEWON

 1. Salaye itumo aroko onisorogbesi
 2. Ko eya ara mefa ti a fi n ba eeyan soro marun-un pelu alaye.
 3. Se itupale ori keta ati ekerin ninu iwe ti o n ka.

 

ISE ASETILEWA

 1. Lara abuda aroko onisorogbesi ni (A) o maa n ni akopa bi ere inu itage (B) o maa n dun (C) ki i ni ipari (D) oro pupo maa n wa nibe.
 2. Itumo ki won fi aso ibora eni ranse si eniyan ni ki eni naa (A) wa sun nile (B) maa sun ita (C) maa sun eyin (D) maa gbe ni eyin, pe won ti ko o.
 3. Eni ti o maa n fi opa ase paroko ni (A) ijoye (B) olori ebi (C) oba (D) igba keji oba.
 4. Itumo ki won fi irukere ranse si eniyan ni wi pe (A) ki onitohun maa bo (B) oba n pe e (C) eni naa ni oye oba kan (D) won juba eni ti won fi irukere ranse si.
 5. Onka ‘eefa’ tumo si (A) ife (B) ifa (C) ki eni naa ma fa wahala (D) ifaseyin.

 

APA KEJI

 1. Salaye itumo aroko onisorogbesi.
 2. Ko ona ibanisoro marun-un pelu apeere.
 3. Salaye lori ori keta iwe apileko ti o ka. (A) (B) (C) (D)

 

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Get Fully Funded Scholarships

Free Visa, Free Scholarship Abroad

           Click Here to Apply

Acadlly