Ise ni oogun ise
Eni ise n se ko ma b’Osun
Oran ko kan t’Osun
I baa b’Orisa
O di’jo to ba sise aje ko to jeun
“Owuro lojo, ise la a fi i se ni Otuu’Fe”. Kaakiri ile Yoruba, ise ni won n fi owuro se. won gbagbo wi pe ‘Ise loogun ise’. Eredi ti won fi mu ise abinibi won ni okunkundun. Se ‘eni mu ise je, ko sai ni mu ise je’. Iran Yoruba lodi si imele, won gbagbo wi pe ‘owo eni ki i tan ni je’. Bi onikaluku ba ti ji idi ise ni won n gba a lo nitori ‘idi ise eni ni aa ti mo ni lole.’ Ibi ti baba bat i n sise ni omo yoo ti maa wo owo re, ti yoo si tibe maa ko o. won ni “Atomode de ibi oro n wo finnifinni, atagba de ibi oro n wo ranran.’ Owe yii fi han wa pe ko si ohun ti a fi omode ko ti a si dagba sinu re ti a ko ni le se daadaa. Eyi ni ise abinibi.
PATAKI ISE ABINIBI
- Oje ise to se fi le omo lowo bi ise asela tabi ona ola
- O n dana airise se laaarin ebi. Ko fi aaye sile fun arinkiri awon ewe. Yoruba ni: “Owo to ba si dile, ni esu n ya lo”.
- Ko si pe a n dajo akoko ti omo yoo lo lenu ekose. Lati kekere ni yoo ti bere; ko si to ya ise lodoo baba re, yoo ti di okunrin, okan re yoo si ti bale si ise naa ni sise. Opolopo ise to ba n se, baba re ni yoo maa se sin titi ti baba re yoo fi ya ise fun-un. Ninu iwe wa kin-in-ni, a pin ise abinibi si isori merin wonyi:
Ise Agbe, ise ode, ise ona ati ise owo. Awon ise abinibi ile Yoruba ti a o yewo siwaju sin i: Ise Agbe, Ise Ajorin, Ise Alapata, Ise Onisowo, Ise Akope ati Ise Gbenagbena.
- ISE AGBE
Ise agbe ni ise ti o gbajumo julo ninu ise ti won n se ni ile Yoruba. Awon agbe ni won n sogbon ounje, ti won n pese ounje fun awa eniyan. Ounje ti a n je ni o n fun ara wan i okun ati agbara lati sise oojo. “Ona ofun, ona orun”. Bee ni ‘bi ebi bat i kuro ninu ise, ise buse’.
PATAKI ATI IWULO ISE AGBE
- Ipese Ounje
- Ipese ohun elo fun awon ile-ise
- Ipese ohun amusoro aje
- Ipese ise
Agbe pin si orisii meji wonyii:
(i) Agbe Alaroje: Iwonba oko ti won yoo fi bo enu ebi ni agbe alaroje n da. Won n gbin agbado, ege, ogede, ata ati ewedu. Eyi ti won ba je ku ni won n ta ni oja fun ara ilu.
(ii) Agbe Alada-Nla/Oloko-Nla: Awon agbe wonyii ni awon ti n fi ise agbe sise se, ti won n da oko nla, ti won si n kore repete. Bi won se n ta ni oja adugbo, ni won n ko won on koja si ilu miiran. Awon agbe yii maa n gba opolopo osise onise odun. Won le ra eru tabi ki won ya iwofa.
ORISII ILE TI AGBE N DA
- Ile Igbo: Ile igbo/egan dara fun ogbin igi owo bii koko, obi, orogbo, ope, osan, kofi, roba, agbon.
- Ile Odan: Ile odan tabi papa dara fun ogbin agbado, isu, ege, egunsi, eree, okaa-baba, owu, epa, anamo ati eso bii mangooro, opeyinbo ati bee bee lo.
- Ile Akuro: Ile akuro dara fun ogbin agbado, ila, ata, efo lorisirisi, ireke, ati awon eso bii oronbp, mangooro ati bee bee lo.
ORISII OKO
Orisii oko meji to wa ni:
(i) Oko Egan: Oko egan ni oko titun ti enikan ko ti i da ri. Igbo kijikiji ni. O maa n jinna si ile. Won maa n ni ahere ti won le seun tabi maa gbe, ti won yoo si maa wale ni osoosu, tabi leekan lodun. Awon ni a n pen i ‘Ara-oko’ tabi ‘Agbe-Arokobodunde’.
(ii) Oko Etile: Oko etile ki fi bee jinna si ile. Awon ti n da oko etile ki saaba sun ni oko. Bi won ba lo ni aaro, won le pada si ile ni ale. Opo igba ni oorun tanmode-soko maa n mu won on di orun si oko.
OHUN ELO ISE AGBE: Oko, Ada, Akoko, Aake, Idoje ati Obe
Awon isoro to n doju koi se agbe
- Airi ohun-elo idako igbalode lo: Ada, oko ni won si n lo. Won ko ni anfaani lilo ero katakata iroko, ikobe, oogun ifinko, ipako ati bee bee lo.
- Ayipada Oju Ojo: Oda ojo ni akoko ti ko ye tabi ojo arooda maa n se akoba fun ikore agbe;
- Awon Eranko: Awon eye, kokoro ati awon eranko bii oya maa n ko lu oko, ti won si le mu ki oko, ti won si le mu ki oko maa se daadaa.
Agbe ni Ode-Oni: Ni ode-oni, tabi-tijoye, tokunrin-tobinrin ni won n sise agbe nitori irorun to de ba ise naa.
Awon ero katakata, ero-irole, tabi ikobe wa kaakiri ti won le ya ni owo pooku. Bee ni oogun igbalode buu ajile, korikori, taritari wa fun awon agbe onikoko.
Awon onimo ijinle, egbe alajosepo, ile ifowopamo ati egbe alajaseku wa ti won n ran awon agbe ni owo fun itesiwaju ise won.
- ISE AJORIN
Ise ajorin ni awon ti won n sise irin jijo, ti a mo si ‘Weda’ ni ode-oni. Bi a pe won ni alagbede, a ko jayo pa nitori igbe kan naa ni ode won n de. Ise yii lowo lori pupo.
IWULO ISE AJORIN
- Bi ko si ajorin, awon agbe ko le sise. Awon ni won n jo ada, akoro, aake tabi obe to ba kan, tabi oko ti o bay a.
- Ni ode-oni, awon ajorin igbalode ni won n jo irin geeti ati ferese ile.
- Awon naa ni won n jo awon ibi ti o ba je ni ara oko oju omi, oju-irin ati ti ori-ile, tatapupu, omolanke ati bee bee lo.
OHUN ELO WON: Ni aye atijo irinse alagbede ko ju owu, omo owu, iponrin, ewiri, emu ati eesan lo. Awon ajorin ode-oni n lo ina gaasi ati kanbaadi, irin ati bee bee lo.
ILANA IKOSI: Niwo igba to je ise abinibi, kekere ni omo won yoo ti maa fi oju si ise yii. Igba ti o ba dagba ni yoo to da ise ya.
- ISE ALAPATA
Ise alapata je ise abinibi awon iran kan ni ile Yoruba. Awon okunrin ni won po nidii ise yii, bi o tile je pea won obinrin naa ko gbeyin ninu owo eran tita. Ise alapata je mo ise eran pipa, eran tita. Maluu pipa ni a mo won mo teleteleeri. Sugbon ni ode-oni won ti n pa ewure ati agbo ta. Won tile ti n ni awon odo-eran ti won ti n pa awon eran wonyi.
PATAKI ISE ALAPATA
- Nipase awon alapata ni eran se n wo ile Yoruba lati oke oya ni opo yanturu. Awon ni won n seto bi won se n ko Maluu, Agbo ati Ewure wole.
- Eni to mo oju ogun ni pa obi ni ‘Re’. Awon alapata ni won mo ogbon mimu awon eran wonyi ti won ba ja ni oriso, bi a se n pa won ati kikun won.
- Ise kekere ko ni eran-jije n se ni ago ara. O n fun ara wa lokun, mu ki ounje wu ni je.
AWON OHUN ELO ALAPATA
- Obe: Obe to mu sarasara ni won fi n pa eran yoowu ti won ba fe pa. obe naa ni won fi n kun un si iwon esipon ti a fe.
- Ada: Ibi to le ni ara eran ni won n fi ad age. Bi apeere, ese eran, ori ati beebee lo
- Aake: Ise kan naa ni alapata n fi aake ati ada se. aake wulo lati fi sa egungun ti ada ko ran tabi to le ba enu ada je. Won le fi aake fo ori Maluu, ese tabi eyin re.
ILANA IKOSE: Awon omo alapata maa n koi se yii lati kekere. Bi omo bas i se n dagbe si ni yoo maa mo apadelude ise siwaju sii. Ise yii yoo gba omode ni odun marun-un si mefa ki o to le gba ominira.
- ISE ONISOWO (OWO-SISE)
Okan ninu awon ise abinibi aye atijo ni owo-sise. Awon iran Ijesa ni a ko mob ii onisowo aso. Awon ni a n pen i ‘Osomaalo’ ni aye atijo. Awon onisowo ni won n ra, ti won si n ta oja fun awon eniyan. Awon obinrin ni won po ju lo nidii ise-owo.
Ise owo pin si orisiirisii. Alajapa ni a n pe awon ti won n ra tabi ya nnkan oko bii koko, ogede, isu, elubo, gaari, osan ati bee bee lo. Awon miiran n sowo ate. A n pe won ni ‘alate’. Awon miiran si wa ti won je onisowo aladaa-nla, ti won n ta aso-ofi, bata ati bee bee lo. Bee ni eran-osin bii ewure, agbo, maluu, eja, bee ni awon miiran n sowo re. ise owo ni owo lori pupo.
PATAKI ISE ONISOWO
- Won n je ki oja da arowoto awon onraja ni asiko
- O n pese ise asela fun ontaja
- Ko mu pakanleke lowo, bi eniyan ba se karamasiki oja to ni a yoo se ta si.
OHUN ELO ISOWO
- Owo-idokowo: Owo ni a fi n pinle owo. “Bi owo bas i ti mo ni oogun un mo”. Bi owo ti a fi bere wow ba se po to nioja eni yoo se tobi si.
- Ibi Isowo: Ibi ti a o ti maa se owo se pataki. O le je inu oja, iwaju ile eni tabi ni irona. Ibe gbodo je ojutaye, ti oja wa yoo ti ta.
- Ipolowo Oja: ‘Ipolowo oja ni agunmu owo’. Awon onisowo maa n kiri tabi pate oja won ki a le mo ohun ti won n ta, ki aje le bu igba je.
ONA IKOSE: Omo le koi se-owo ni owo obi bi ise abinibi tabi ki o lo ko o bi awose. Won ni ‘Bi a se n kose ni a ko iyara’. Ijafara se pataki nidii ekose owo.
- ISE AKOPE
Ise ohunrin ni ise akope. Okan ninu awon ise ti a ba lowo awon baba-nla wa ni. Tokunrin-tobinrin ni won mo riri ise yii. Awon ni won n ko eyin ope ti a fi n se epo-pupa. Ise elege ni.
Ise yii gba suuru ati aya nini. Eniyan to ban i ooyi oju ko le sise akope. Igba miiran wa ti owo palaba akope le segi, ki igba ja, tabi ki ese ye ni ara igi ope tabi ki ejo nla san won ni ori ope. Gbogbo nnkan wonyi lo le fa ki akope jao. Koko bii irin sin i idi igi ope maa n le. Idi niyi ti o fi je wi pe opo eni ti o ba ja lati ori igi ope ki i fi i ye. Eegun eyin tabi ti ibadii le kan, tabi run yegeyege. Idi igi ope naa ni won n sin oku bee si.
PATAKI ISE AKOPE
- Ipese epo isebe: Epo ni iroju obe. Bi ko si akope, obe efun ni a ba maa je.
- Ipese Owo ati Apere: Imo ti akope ge lule lati ori igi open i a fi n fa owo ti a tun n fi ifon re hun apere. Bi owo ko si bi akitan ni ilr ati ayika i ba da. Bi agbon ko bas i ni ahere, owo ni a ba fi ko isu wale.
AWON OHUN ELO AKOPE
- Igba: Igba ni okun agba ti won lo pot i akope fi n gun igi ope. Igba yii maa n gbopon, bee ni a maar o.
- Aake: Aake ni akope n fi i re imo danu, ki o le ri aaye geo di eyin lule.
- Ada: Akope le fi ad age imo ori ope, bakan naa ni o le fi sa odi eyin lule.s
EKOSE: Bi o tile je omode le maa fi oju si bi won se n gun ope, o gbodo di gende ki o le da ko ope. O le bere lati ori opekete. Eyi ni ope kekere ti owo lee to eyin ori re ni ile. Won ni “Opekete n dagbe, inu adamo n baje”.
- ISE GBENAGBENA
Ise gbenagbena je okan pataki ninu ise ti a ba lowo awon baba-nla wa. Awon okunrin ni won n sise yii. Ise yii je ise ti toba-tijoye n karamasiki re. awon ni won n gbe igi opo-ile, ilekun, apoti ijokoo Oba. Won le fi igi gbe Ekun, Ologbo, Odidere, Erin ati orisirisii ere, apeere awonti a n ba pade ni aafin Oba tabi ilea won olola ati awon ijoye. Awon ni won n gbe opon-ayo, opon-ijeun, orisii ere fun ilo awon ara ilu ati awon ti a n ri ni iyara ikohun-isebaye-si bi eyi ti o wa ni Ile-Ife ati Binni. Gbenagbena naa ni won n se eeku ada, igi oko, igi aake ati bee bee lo fun ilo awon agbe. Owo tabuu ni won n pa.
PATAKI ISE GBENAGBENA
- Ko je ki asa wa lo si okun igbagbe
- O je ona ipawo wole si apo gbenegbena
- O je ona ipawo wole fun Ijoba, ti wo ba fi awon ere wonyii sowo si oke okun
- O pese ise fun awon odo
AWON OHUN ELO WON:
- Aake: Aake ni gbenagbena fi n ge igi ti won fi n gbe ere lule, ti won yoo sig e si orisiirisi ike
- Ada: Ada ni a n lo dipo aake lati ge igi ti a fe lo si ike-ike. Ohun naa ni a fi n bere ere gbigbe
- Obe: Ti ise ba de ibi elege bii ki a fe se oju, imu, eti, enu, oyan-aya, obe ni a n lo. Oun ni won fi n gbe ara nnkan, ki o le dan daadaa. Bi won se ni obe nla ni wo ni kekere ti won fi n dan ara ere tabi opa itile.
- Osese: Oseseni a fi n da iho sinu igi ti a fe fi gbe ere tabi ara nnkan miiran ti a fe gbe
Orisii Igi ti won n lo
- Igi Iroko tabi Oganwo: Igi wonyi le pupo. Awon ni a fi n gbe odo, opa itile.
- Igi Awun: Igi yii ko le koko bii igi iroko tabi oganwo. Oun ni a fi n gbe ere, opon-ayo.
ILANA IKOSE: Awon ti won ba je omo gbenagbena le bere lati kekere. Won yoo si lo to odun mewaa ki won to mo ise naa dunju. Awon ti won wa ko ise yii bi awose yoo lo bii odun marun-un si mefa ki o to gba ominira.
Ni ile Yoruba, ni ojo igbominira, ti o ba je ise awose, oga yoo fi oti ibile tabi oyinbo gba adura fun omo ekose. Awon obi omo-ekose naa yoo gbe ohun jije-mimu kale lati je ki won mu.
ISE AMUTILEWA
- So pataki ise isenbaye
- So iwulo ise abinibi meta
- So orisii ise abinibi meta ki o si daruko ohun elo ise won
- So pataki ise agbe marun-un
See also
AKORI EKO: ATUNYEWO LORI SILEBU EDE YORUBA
AKORI EKO: AROKO AJEMO – ISIPAYA