AKORI EKO: ATUNYEWO IHUN ORO
Iro konsonanti ati iro faweli pelu ami ohun ni a n hun po di oro. Orisi oro meji ni o wa ninu ede Yoruba. Awon ni:
- Oro ipinle; ati
- Oro ti a seda
- ORO IPINLE: Oro ipinle ni awon oro ti a ko le seda won. Apeere:
Adie, eedu, omi, ori, oju, imu, eti, apa, ese, owo, ile, oba, odo, ojo, agbara, omo, iya ati bee bee lo.
Abuda Oro Ipinle
- Oro-ipinle maa n ni itumo kikun
- A ko le seda won. Bi apeere:
Iya: a ko le so pe *i+ya lo di ‘iya’
Ori: a ko le so pe *o+ri lo di ‘ori’
Omo: a ko le so pe *o+mo lo di ‘omo’
Oba: a ko le so pe *o+ba lo di ‘oba’
Oro ti a seda ati oro-ipinle awon oke yii ko ni ijora itumo. Idi niyi ti a fi pe won ni oro ipinle ti a ko le seda rara.
- ORO ASEDA: Eyi ni awon oro-oruko ti a seda nipa lilo afomo tabi oro miiran.
Abuda oro ti a seda
- Oro aseda maa n ni oro ipinle ati afomo tabi oro miiran ti a fi kun un. Apeere:
Afomo ibeere Oro-Ipinle Oro ti a seda
a + de = ade
o + re = ore
(ii) Oro ipinle ati oro-oruko ti a seda gbodo ni ijora itumo. Apeere:
Oro-Ipinle Oro ti a seda
a + de = ade
o + re = ore
(‘de’ ati ‘ade’ ni itumo ti o jade. ‘de’ tumo si ki a fi nnkan bo nnkan ni ori; ‘ade’ ohun ti a de. ‘re’ ati ‘ore’ ni ijora itumo)
ORISII ONA TI A N GBA SEDA ORO-ORUKO
A le seda oro-oruko nipa awon ona wonyii:
- Lilo Afomo
- Akanpo Afomo Ibeere ati Oro Ipinle. Akanpo bee yoo di oro-oruko. Bi apeere:
Afomo Ibeere | Oro Ipinle/Oro-Ise | Oro-oruko ti a seda |
A a o o ϙ ϙ ai ai on on ati | Yo se sise ku gbon re sun gbagbo te kawe je | ayo ase osise oku ogbon ore aisun aigbagbo onte onkawe atije |
- Akanpo afomo Ibeere ati ipinle to je oro-oruko tabi aropo afarjoruko. Apeere:
Afomo Ibeere | Mofiimu Ipinle | Oro-oruko ti a seda |
oni oni oni ti ti | Iranu eja aso emi eyin | oniranu eleja alaso temi teyin |
- Akanpo afomo ibeere ati oro ipinle to je oro-oruko tabi aropo afarajoruko. Apeere:
Afomo Ibeere | Oro-Ise | Oro-Ise | Oro-oruko ti a seda |
A i i | Da tan gba | ko je la | adako itanje igbala |
- Lilo Afomo Aarin: ‘ki’, ‘de’, ‘ku’, ‘si’ ni aarin apetunpe oro ipinle to je oro-oruko. Apeere:
Mofiimu Ipinle | Afomo aarin | Mofiimu ipinle | Oro-oruko ti a seda |
Ile owo iran oro iwa eniyan | Si de de ki ki ki | ile owo iran oro iwa eniyan | ilesile owodowo irandiran orokoro iwakiwa eniyankeniyan |
(ii) Sise Apetunpe Kikun. Eyi le waye nipa:
- Apetunpe Oro-Oruko
Oro-Oruko | Oro-Oruko | Oro-oruko ti a seda |
iya ose odun osu ogorun-un | iya ose odun osu ogorun-un | Iyaaya Osoose Odoodun Osoosu Ogoogorun-un |
- Apetunpe Apola-Ise
Apola – Ise | Apola – Ise | Oro-oruko ti a seda |
jaye gbomo wole pana | jaye gbomo wole pana | jayejaye gbomogbomo wolewole panapana |
(d) Apetunpe Elebe: Eyi n waye ti a ba fe dunrun mooro-ise. A o so oro-ise to je mofiimu ipinle di meji, ki a way o faweli ara oro-ise akoko sonu, a o wa fi faweli ‘i’ olohun oke ropo re. bi apeere:
Oro – Ise | Konsonanti to bere oro – ise | Mofiimu ‘i’ | Oro-oruko ti a seda |
Ra ka bi we | R k b w | i i i i | rira kika bibi wiwe |
(iii) Sise Akanpo Oro – Oruko. eyi le waye nipa:
- Akanpo oro-oruko meji inu eyi ti aranmo yoo ti han
Oro – oruko | Oro – oruko | Oro-oruko ti a seda |
owo ona agbo ewe | ile ile ile obe | owoole onaale agboole ewebe |
- Abranpo Oro-oruko meji inu eyi ti aranmoyoo ti han
Oro – oruko | Oro – oruko | Oro-oruko ti a seda |
ara enu irun | Iwaju ona agbon | araawaju enuuna irungbon |
(d) Akanpo Afomo Ibeere ati Apetunpe Oro-Oruko. Apeere:
Afomo Ibeere | Oro – Oruko | Oro – Oruko | Oro-oruko ti a seda |
oni oni | ojumo osu | ojumo osu | olojoojumo olosoosu |
(e) Akanpo Afomo Ibeere ‘oni’ mo oro-oruko meji. apeere
Afomo Ibeere | Oro – oruko | Oro – Oruko | Oro-oruko ti a seda |
oni oni | ori aya | ire oba | oloriire alayaa |
(iv) Sise asunki odidi gbolohun di oro-oruko. apeere
Gbolohun | Oro-oruko ti a seda |
Oluwa to sin A kuru yejo | Oluwatosin Akuruyejo |
(v) Siso oro-oruko onigbolohun po. Apeere:
Ifa ni eti – Faleti
Oye ba mi ji – Oyebamiji
Aje wo ile – Ajewole
(vi) Lilo ami asoropo oro onigbolohun. Apeere
a-duro-sigidi-koogun-o-je
a-losoo-gongo-je’su-eba-ona.
ISE AMUTILEWA
- Se itupale akojopo oro-oruko eniyan ti a seda wonyii:
- Faleti
- Omolola
- Ifeolu
- Titilayo
- Ilesanmi
- Iluyomade
- Adeoti
- Olukoyejo
- Adeyemi
- Oladiran
- Pin awon oro-oruko wonyi si eyi ti a seda ati eyi ti a ko seda
- Igunpa
- Imu
- Aso
- Oguntoye
- Oko
- Ese
- Oju
- Inufele
- Erupe
- Eti
See also
AKORI EKO: AROKO ONI-SORO-N-GBESI
AKORI EKO: ATUNYEWO ISE ABINIBI
AKORI EKO: ATUNYEWO LORI SILEBU EDE YORUBA
AKORI EKO: AROKO AJEMO – ISIPAYA