AARE BOOLU

Femi:         Boolu ale yii ko yoyo, o dun yato. Abi?

Bayo:         Bee ni. Mo gbadun re gan an ni. Ki lo ri si ayo ti Kola gba wole ti Refiri fagi le un?

Femi:         Mo rii. O dun mi wonu eegun. O dabi eni pe Refiri ti fon fere ki Kola to gba boolu naa s’awon.

Pari iforowero yii. Lo awon gbolohun ibeere ati ede iepri to je mo are boolu afesegba.

 

 

 

 

 

 

AKORI EKO: ONA IBANISORO

Ibanisoro ni ona ti eniyan meji tabi ju bee lo n gba fi ero inu won han si ara lona ti o fi ye won yekeyeke. Ona yii ni a n pen i ede. Ede ni o n fun ohun ti a n so ni itumo. Bi eni meji ti won ko gbo ede ara ba n soro, bi ariwo lasan no ohun ti won n so.

Ni aye atijo, awon baba-nla wa kii fi gbogbo enu soro. Won gba wi pe ‘gbogbo aso ko la n sa loorun’. Awon ona kan wa ti won n gba ba eni to sun mo won, to wa nitosi tabi ona jijin soro lai lo enu. Se “Asoku oro ni je omo mi gb’ena”. Won a maa lo eya ara tabi fi nnkan miiran paroko ranse si won, ti itumo ohun ti won soyoo si ye won.

Ni ode-oni ewe, irufe ona ibanisoro yii wa, bi o tile je wi pe ona igbalode ni won n gbe e gba. Gbogbo nnkan wonyi ni a o yewo finnifinni.

 1. ONA IBANISORO NI AYE ATIJO
 2. Lilo Eya Ara fun Ibanisoro: Eya ara ti a n lo fun Ibanisoro je awon eya ara ti a le gbe soke-sodo, ti eni ti a n fii ba soro le ri. Eni bee le wan i egbe eni tabi wa nibi ti ko jinna. Apeere awon eya ara naa niwonyi:

(i) Oju: Oju se pataki ninu eya ara ifo. Bi apeere, a le fi oju fa ‘ni mora’, kilo fun eniyan bee ni a le fi na eniyan lailo pasan. Eni ti o ba kuna lati mo eyi ni won n bun i alaimojumora. Bi apeere,

AMI ITUMO/ALAYE
Ti a ba n soro, ti a wa se oju si eni naa Ki o joo, gbe si mi leyin

Ki o dake, pe enikan n bo

Ti a bam o eniyan loju N ko gba tire. Ami ija ni eyi

N ko fara mo oro ti o n so

Fe oju mo omode A fi n deru ba a ni
Ti a ba fi odo oju tabi oju isale wo eniyan Ami ife ni. Okunrin le fi oju isale wo obinrin.

 

(ii) Ori: Ipa pataki ni ori n ko bii ona Ibanisoro. Igba miiran, eniyan le so ori ko, won a ni oluware n ronu. Bi o ba n fi owo ja ori, to n fi ese jale, ajalu laabi kan ni o sele sii. Bi apeere:

AMI ITUMO/ALAYE
Ti awon eniyan bag be ori so si nnkan ti a n se O dara. Maa se lo
Ti won ba gbon ori Ami ikaaanu ni naa tabi ilodi si nnkan to n se.
Ori gbigbon Rara o. lati fi ilodi si han
Ti won ba bi wa leere oro, ti a mi ori Tooto ni. Bee ni, tabi bee ko
Ti a ba mi ori si isale A pe eniyan pe ki o wa
Ori mimi sotun-un, sosi Rara o tabi bee ko

 

(iii) Imu: Yoruba kii dede yin imu ti ko bas i ija tabi ikunsinu. Bi apeere:

AMI ITUMO/ALAYE
Ti a ba yinmu si eniyan A n fi eni naa sefe ni, wi pe a ko ka oro ti eni naa n so si rara

 

(iv) Enu: A le lo enu lai ya a tabi sii raa. Bi apeere:

AMI ITUMO/ALAYE
Ti a ba yo suti tabi yege enu si eniyan A n fi eni naa se yeye ni tabi pe oro eni naa ko mu ogbon wa
A le fi enu sufee Ko si oro ti a ko le fi so

 

(v) Ejika:

AMI ITUMO/ALAYE
Bi a ba n ban ii soro ti a gbun tabi so ejika Mo gba oro naa wole bii otito

Mo lodi si oro naa

 

(vi) Ese:

AMI ITUMO/ALAYE
Bi a ba fi ese janle Ami ilodi si nnkan kan ni eyi je
Tite eniyan lese mole A n kilo fun un pe ki o ma se nnkan kan tabi ki o dake

A le fi pe akiyesi re si nnkan kan

Fi ese mole A fi n han pe a ko nifee si ohun ti enikan n so.

 

(vii) Eekanna

AMI ITUMO/ALAYE
Sise ni leekanna Ikilo nip e ki o dake oro tabi fi pe akiyesi re si nnkan kan

 

(viii) Owo: Ilo owo bi ona ibanisoro po. A le ju owo si eniyan pe ki o wa, bee ni o le ya owo kan naa yii lati bun i.

AMI ITUMO/ALAYE
Bi a ba sewo si eniyan Ki o wa tabi ki o duro de wa
Ti a ba juwo si eniyan A n kii ni

A n dagbere fun un pe ‘O digba o se’

A n le eni naa siwaju

Ti a bay a owo si eniyan A n bu iya eni naa ni

(ix) Ete: Orisiirisii ona ni a le gba lo ete lati soro. Apeere.

AMI ITUMO/ALAYE
A le yo suti ete Lati fi saata tabi bun i
A le yo ete si enikan Lati juwe tabi so ibi ti nnkan wa

 

IPAROKO

Aroko je ona kan ti an gba ba ara eni soro ni aye atijo. Bi awon agba ba fe soro asiri ti eni ti won fe so o fun ko si nitosi, tabi ti won ba fe ranse sile ni asiri, aroko ni won n lo. Aroko pipa ranse si ni ko gba sise alaye repete. Aroko ni yoo tumo ara re fun eni ti a ba ran an si.

Die ninu egbaagboje ona ti awon baba-nle wa n gba paroko ranse si eniyan ni wonyii:

(i) Ilu Lilu: Ni ile Yoruba, ilu n koi pa pataki ninu ona ibanisoro ni aye atijo. Ko si ohun ti won ko le fi wi. Ilu ni awon baba-nla wa fi maa n ranse si oju ogun. Bi ogun bag bona janjan, ilu ni won n ki awon asaaju.

(ii) Edan Ogboni: Edan je orisii opa Ogboni kan ti o maa n ni ere ni ori re. bi enikan ba je gbese, ti won wa fi edan Ogboni ranse sii, eni naa ko gbodo jafara bi o bat i rii gba. O ni lati wa owo na san kiakia. Eyi je asa larin awon Egba.

(iii) Opa Ase: Oba nikan ni o n fi opa ase paroko. Nitori pe kii se gbogbo ode ni Oba le e lo, opa ase yii ni Oba maa n gbe ranse lati fi han wi pe oun wa nibe. Bi Oba bas i fe ri enikan ni kiakia, opa ase ni yoo fi ranse sii.

(iv) Irukere: Oba, Baale, Ijoye ati agba-awo ni won n fi irukere paroko. Ti won bay o eyo irun irukere kan, ki won ta ni koko si inu aso pupa, ti won ba fi ranse si enikan, apeere ija tabi wiwa pipon onu eni tabi pe ija n bo niyi.

 • Awo Edun
 • Sigidi
 • Iye Adie
 • Ebiti ati Awo Ehoro
 • Owo-Eyo Meta
 • Aso Ibora
 • Igbale
 • Eepo igi ose ati aso pupa
 • Idaji agbe emu tabi ajadii agbe
 • Esun-isu
 • Igi sisa loge
 • Morinwo tabi Aso Pupa
 • Eni
 • Eeru

Awon aroko to je mo Onka: Iwonyi ni awon ami aroko to je mo onka Yoruba. Apeere:

AMI ITUMO/ALAYE
Eeta Ti a ba fi nnkan meta ranse si eniyan, o tumo si pe a ta onitohun danu.
Aarun-un Awon onifa ni won n lo lati so fun eni naa ki o se kankan lori ohun ti o mu ni paroko naa ki ojo marun-un to pe
Eefa Ami ife ni eyi n toka si. Okunrin le fi ranse si obinrin pe ki awon fi ara mora.
Eeje Ojo ije egungun ati oro. O tun le tumo sip e ki eni ti a paroko ranse si ri ni ki ojo meje to pe
Eejo Bi a ba fi nnkan mejo paroko ranse sin i, to ba je owo-eyo, o tumo si pe ko si ewu loro eni naa nitori ile jo
Eesan-an Ami ki eniyan so ewe agbeje mowo niyi, paapaa si eni to n du oye. A fi so fun un pe “Ilesanmi dun ju oye lo”.
Eewaa Ti a ba fi owo-eyo mewaa ranse si eeyan, o tumo sip e ki o wa. Won ni “Eewaa kii wa eni tire ti.”

 

Awon aroko to je mo awo

Awo Ohun to duro fun
Funfun Nnkan mimo/alaafia
Dudu Nnkan buburu. Obinrin to n sofo maa n wo aso dudu
Pupa Ohun to lewa. Pupo ni aso orisa Sango ati Esu

 

Awon aroko to je mo iro: Awon ohun elo ibanisoro ni a fi n gbe iro jade niwonyii:

Ohun-elo Alaye ilo won
Fere Fere le je eyi ti a fi irin, igi tabi iwo eran se. orisii fere to wa ni: Pakuta, Anbere, Tioko, Kakaki, Turumagbe, Talaka, Ekuku, Ti-an-ko, Iwo ati bee bee lo.

(i)                 Awon ode n fon ekutu ati tioko laarin ara won

(ii)               Won n lo fere lati pe ara won ni igbe ode

(iii)             Won n fon kakaki lati fi ki Oba ni Aafin

Agogo Orisii agogo lo wa:

(i)                 Alagogo Oba maa n lu u lati fi pe eniyan jo lati jise Oba

(ii)               Agogo orun aja ni lati mo ibi ti aja ode wa ninu igbo

(iii)             Agogo ifa ati ilu aran tabi ipese ni awon awo n lo ki ohun didun le jade

(iv)              Agogo ode asode ni lati kede pea won ti gbode

 1. IBANISORO AYE ODE ONI

Ni ode-oni, ede ni opomulero ona ibanisoro. Ede ni a fi n se amulo agbara lati ronu ti a o si so ero inu wa jade fun agboye: ti a fi n salaye ohunkohun. Ohn ni a fi n ba ni kedun, ti a n fi n ban i yo, ohun ni a fi n ko ni lekoo ni ile ati ile-iwe. Ede ni a fi n gbani ni iyanju, ti a tun fi n danilaraya. Pataki ede ni awujo ko kere.

Bi ko bas i ede, redio, iwe iroyin ko le wulo. Ede ni redio ati telifison fi n danilaraya, ti won fi n ko ni lekoo, ti won fi n royin. Olaju esin ati ti eko imo sayensi ti mu aye lu jara nipa imo ero. Awon ona ibanisoro ode oni niwonyi:

 • Iwe Iroyin: Ipa pataki ni iwe iroyin n ko bii ona ibanisoro. Henry Town send ni o koko te “Iwe Iroyin fun awon Egba ati Yoruba” jade ni ede Yoruba ni odun 1859. Eyi ni iwe iroyin akoko ni ede Yoruba. Leyin re ni “Iwe Irohin Eko” ti A.M. Thomas je olootu re jade ni odun 1888. Odun 1891 ni Eni-owo J. Vernal gbe “Iwe Eko” jade. Eyi fi han wipe ojo iwe iroyin tip e ni ile Yoruba.
 • Telifison: Ile Yoruba naa ni Telifison akoko ni ile eniyan dudu ti bere ni ilu Ibadan. Bi oruko re “Ero-Amohun-Maworan” ni a n pe o. anfaani gbigbo oro ati riri aworan awon eniyan inu re wo je iranlowo ti ko ni afirwe ninu gbigbe ede ati asa Yoruba laruge. Ona kaan naa niyi ti a fi gbe ero eni si ori eto, ti ibanisoro si n waye.
 • Redio: Ojo redie naa tip e ni ile Yoruba. Bii oruko re ‘ero-asoromagbesi’, oro lasan ni a n ti won n so ni ori eto okan-o-jokan won. Anfaani wa fun eniyan lati gbe ero won si ori afefe lati fi danilaraya, ko ni lekoo, ni lekoo ati fi laniloye.
 • Pako Alarimole lebaa Titi ati Ina Adari-Oko: Awon patako alarimole wa kaakiri oju popo ti won n juwe tabi dari eni si opopona laarin ilu-nla-nla. Bee ni ina adari-oko wan i ojuu Popo ti won n dari oko. Awon meta ni awon fi n paroko lilo ati diduro oko ni ikorita. Awo pupa duro fun ‘duro’, ewu wa lona; awo olomi osan ni ki a si ina oko ni imura sile lati lo, bee ni awo ewe ni ki oko maa lo.
 • Ero-Aye-Lu-Jara: (Intaneeti). Ero ayelujara je gbagede agbaye to si sile fun teru-tomo, ti a le lo, to si wan i arowoto gbogbo eniyan.
 • Leta Kiko: Leta kiko je aroko aye atijo ni orisiirisii ona. Gbigbe ni a n gbe leta, gbigbe naa ni a n gbe aroko ti a ba di ni gbinrin, titu ni a n tu apo-iwe lata, titu naa ni an tu gbinrin ti a di, kika la n ka leta, wiwo ni a n ami aroko. Igba ti won bat u u ni won yoo to mo ohun to wa nibe.
 • Foonu: Oro naa ni a n so si inu foonu ti eni to wan i odikeji ti a pe n gbo. Bi oun naa ba fesi awa ti a pe naa yoo gbo. Ona ibanisoro yii di ilumoka ni ile Yoruba. A le wan i Eko, ki a ma takuroso pelu eni to wan i ilu Oyinbo!
 • Agogo: Bi o tile je pe agogo je ohun-elo iparoko aye atijo, won si n lo won bi ona ibanisoro ni ode-oni. Bi apeere:

Agogo ile isin lilu –           lati pe eeyan wa josin ni soosi

Agogo omo ile wa –           lati fi pea won akekoo wole

Agogo onisowo      –           lati fi fa onibara won mora.

ISE ASETILEWA

 1. So marun-un lara ona ibanisoro ti o mo
 2. So awon eya ara marun-un ti a fi n ba ara eni soro
 3. Daruko marun-un ni ara ona ibanisoro ni aye ode oni

 

See also

AKORI EKO: AROKO ONI-SORO-N-GBESI

AKORI EKO: ATUNYEWO ISE ABINIBI

AKORI EKO: ATUNYEWO LORI SILEBU EDE YORUBA

AKORI EKO: AROKO AJEMO – ISIPAYA

AKORI EKO: MOFIIMU

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Move to the US or UK (Japa) on a Scholarship

Acadlly
error: Content is protected !!