ITAN NIPA OGUN
Ogun je okan pataki ninu awon okanlenirinwo irunmole ti won ti ikole orun wa si ile aye. A gbo pe nigba ti awon orisa n bo wa si ile aye, won se alabaapade igbo didi kijikiji kan. Orisa-Nla ni a gbo pe o koko lo ada owo re lati la ona yii sugbon ada fadaka owo re se. Ogun ni a gbo wi pe o fi ada irin owo re la ona gberegede fun awon orisa yooku lati koja. Ise ribiribi ti ogun se yii ni awon orisa yii se fi jeoye Osin-Imole ni ile-Ife.
Itan fi han pe ode to ni okiki ni ogun. Tabutu ni oruko iya re. Baba re ni Ororinna. Won ni Ogun feran ise ode sise to bee to fi fi ilu sile lo si ori-oke kan ki o le ri aaye se ise ode. Igba ti ori-oke yii su un ni o pinnu lati pada si Ile-Ife. Igba ti ogun n bo, oju re le koko. Won ni:
‘Ojo Ogun n ti ori oke e bo,
Aso ina lo mu bo ‘ra,
Ewu eje lo wo sorun’.
Eyi ti Ogun iba fi duro ni Ile-Ife, ilu Ire ni a gbo pe Ogun lo. Won si gba a tayotayo. A gbo pe emu ni Ogun ko beere nigba ti o de Ire. Won fun un ni ounje ati emu mu. Idi niyi ti won fi n so pe: ‘Ire ki i se ile Ogun, o yak i won nibe menu ni’. Ori oke ninu igbo kan ni Ogun tun lo do sin i Ire. Bi o ba n bow a si aarin ilu, mariwo ni o maa n fi bora. Idi niyi ti won fi n ki i ni: ‘O-laso-nile fimokimo bora, Mariwo yegbeyegbe laso ogun’.
Orisirisi oruko ni won n pe Ogun. Ogun ni won tun n pen i Lakaaye; Osinmole, Awoo, Olumokin, Yankanbiogbe ati bee bee lo.
IGBAGBO YORUBA NIPA OGUN
- Ogun ni orisa to ni irin. Gbogbo awon ti won n fi irin se je ti ogun.
- Oun lo la ona fun awon orisa elegbe re
- Orisa to feran ododo ati otito
- Orisa ogun ni Ogun
- Gbenagbena ni Ogun
ODUN OGUN
Kari ile Yoruba ni won ti n se odun Ogun, sugbon o gbayi ju lo ni awon ilue bii Ondo, Ilesa, Ile-Ife, Akure ati Ekiti. Akoko isu titun ninu osu keje si ikejo odun ni won n se odun Ogun.Ilu Agere, Katakoto ati bembe ni ile Ogun.
AWON OHUN TI WON FI N BO OGUN
Aja, Esun isu, epo, adiye, agbo, ewure, eyele, igbin, ewa eyan, iyan, obi abata, orogbo, ataare ati emu. Eekan soso ni apaja ogun gbodo be aja ni orun ti won ba n bo Ogun.
OJUBO OGUN
Awon ohun ti a n ri ni ojubo orisa yii ni omo owu, opa ogun, emu sekele, ada, ibon,obe, irin, olugbondoro, awon nnkan ija ogun.
BI WON SE N BO OGUN
Bi won se n bo Ogun ilu naa ni won n bo Ogun idile kookan. Okuta ribiti lo duro fun Ogun Agbede. Ori re ni awon alagbede ti n ro oko ati ada. Irin wewe ti a ko jo sinu ate Ogun lo duro fun ‘Ogun Ate’.
ORIKI OGUN
Ogun lakaye. Osin Imole
Ogun alada meji
O fi okan san’ko
O fi okan ye’na.
Ojo ogun n ti ori oke bo
Aso ina l’o mu bora
Ewu eje lo wo.
Ogun onile owo, olona ola
Ogun onile kangunkangun orun
O pon omi s’ile f’eje we
Ogun awon l’eyinju’
Egbe l’ehin omo kan,
Ogun meje l’ogun mi,
Ogun alara ni igba ‘ja,
Ogun Onire a gbagbo
Ogun ikola a gba’gbin
Ogun Elemona ni i gba esun’su
Ogun Aki’run a gba iwo agbo
Ogun Gbenagbena eran awun ni i je
Ogun Makinde ti d’Ogun l’ehin odi,
Bi ko ba gba Tapa, gb’Abooki,
Agba Uku-uku, agba Kemberi,
Nje nibo l’a ti pade Ogun?
A pade Ogun nibi ija,
A pade Ogun nibi ita;
A pade re nibi agbara eje n san,
Agbara eje ti i de ni lorun bi omi ago
Orisa t’o ni t’Ogun ko to nkan
A f’owo je’su re nigba aimoye…
See also
AKORI EKO: ITESIWAJU EKO LORI ONA IBANISORO