AKORI EKO: IHUN ORISIIRISII AWE GBOLOHUN PO DI ODIDI GBOLOHUN

Kin – in – ni awe gbolohun?

Awe gbolohun ni ipede to ni oluwa ati ohun ti oluwa se

Bi apeere:

Ayinke mu omi

Adepoju ti jeun

Kasali je eba

Awe gbolohun le je ipede ti ko ni ju apola oro oruko ati apola kookoo lo. Apeere:

Mo gba ebun naa

Awon ni won wa

Ade ti sun lanaa

Mo                               gba      ebun    naa

apola                           apola   oro – ise

oro-oruko                    (verb phrase)

(Noun phrase)

 

Awe gbolohun le da duro ki o ni itumo. Apeere:

Isola ati Ajani ra aso

Omi ero naa mo

Awe gbolohun miiran le da duro ki maa ni itumo (awe gbolohun afarahe)

Ti a ba ko ile

Iba ke si mi

Yala o wa tabi ko wa

Awe gbolohun le da duro bi odidi gbolohun, iru awe gbolohun bee ni a maa pe ni olori awe gbolohun. Apeere:

Won gba

Ade mo

Iya omo ni

 

Itesiwaju ise lori awe gbolohun Abeke gbon

Opolopo awon gbolohun abode ni o le se ise awe gbolohun. Sugbon kii se gbogbo awe gbolohun lo le da duro bii gbolohun. Awon gbolohun isale wonyi le se ise awe gbolohun.

Akanmu mu emu

Apinke se iresi

Ode pa igala

Orisii awe gbolohun (Types of clause)

  1. Olori awe gbolohun (main clause): Eyi maa n da duro, o si maa n ni itumo ati paapaa o maa n sise odidi gbolohun. O ti ihun jo gbolohun abode tabi gbolohun eleyo oro-ise. Bi apeere:

Awon omode feran iresi

Aja Ogundeji ku

Ise dara

  1. Awe gbolohun afarahe (subordinate clause): Inu ihun gbolohun olopo oro-ise tabi gbolohun onibo ni a ti maa n ri awe gbolohun afarahe. Ninu gbolohun olopo oro – ise. Ipa kan yoo je gbolohun kikun nigba ti awon iyoku yoo je awe gbolohun afarahe ti ko ni itumo.

 

Orisii awe gbolohun afarahe

  1. Awe gbolohun afarahe asapejuwe: ti ni atoka ibeere awe gbolohun yii. Awe gbolohun yii maa n tele oro oruko tabi apola oruko, o maa n je ki a mo nipa apejuwe nkan. Bi apeere

Apinke ti o sun ti dide

Aso Ankara ti mo ra dara

Omoge ti mo n soro re niyi

  1. Awe gbolohun afarahe asodoruko: ‘Pe’ ni o maa n bere awe gbolohun yii, o le sise oluwa ati abo, o si maa n sise iso – doruko ninu ihun gbolohun. Apeere:

Pe Olu ku ti mo gbo igbe ni mo fi ta

Pe oju ka awon ole naa mo dun mo mi

Oda mi loju pe omo naa ko le jale

iii. Awe gbolohun afarahe asaponle: Awon oro atoka fun awe gbolohun yii n ‘nigba’, ‘ti’, ‘nitori ti’ abbl. Awon oro – ise ti won maa n tele gbolohun ni won maa n pon. Bi apeere:

Aja naa ku nigba ti oko ko lu u

Emi yoo lo nisinsinyii ti mo gbo pe won de

Ole naa ku nigba ti olopaa kolu won

Obrinrin naa ku nitori ko ri owo le iwosan san

 

 

Iyato ti o wa laarin apola ati awe gbolohun (Differences between phrase and clause)

APOLA (PHRASE) AWE GBOLOHUN (CLAUSE)
1. Apola kii ni oro – ise (ayafi ninu apola ise) Bi apeere:

Iya Joke

Aburo Badejo

Ni Ibadan

Awe gbolohun gbodo ni oro – ise ninu. Bi apeere:

Ki o to sun

Ti mo ra

Maa jo

2. Apola ko le da duro ki o fun wan i itunmo kikun. Bi apeere:

Ni abule odu

Papa asafa

Aja ode

Rin kemokemo

Olori awe gbolohun le da duro ki o fun wan i itumo kikun. Bi apeere:

Mo ti de

Fijobi kan ilekun

Aso Ankara dara

3. Apola ko le daduro bi odidi gbolohun kikun. Bi apeere:

Iwo ati emi

Ni Osogbo

Ti ile bo

Olori awe gbolohun le da duro bii gbolohun kikun ti o ni itumo. Bi apeere:

Obinrin yii burewa

Egungun ko korin

Adeojo kii ja

 

See also

OSE KEFA ETO IGBEYAWO ABINIBI

ORISII ONA TI A N GBA SOGE NILE YORUBA

ETO ISELU ODE-ONI

ETO ISELU ABINIBI ATI ODE ONI

ISEDA ORO-ORUKO

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Move to the US or UK (Japa) on a Scholarship

Acadlly
error: Content is protected !!