OSE KEFA ETO IGBEYAWO ABINIBI

ASA IGBEYAWO ATIJO (IBILE)

IGBESE IGBEYAWO                                 ALAYE

Ifojusode                    Awon obi okunrin yoo maa fi oju sile wa obinrin.

Iwadii                         Won yoo se iwadii idile obinrin naa ni aarin ilu. Won yoo tun se,

iwadi lowo ifa.

Alarina                       Alarina ni won yoo maa ran si ara won (oko ati Iyawo afesona), Boko ba

moju aya tan, alarina a yeba.

Isihun/ijohen Gbigba ti obinrin gba lati fe okunrin.

Itoro                            Awon ebi okunrin yoo wa toro omobinrin ni owo obi re.

Baba gbo, iya Awon ebi mejeeji gbo, won si gba pe ki obinrin ati okunrin fera

gbo 

Idana                          Ebi oko yoo gbe eru idana lo fun ebi omobinrin ti ojo igbeyawo won

ba ku feere. Isu ogoji, orogbo ogoji, obi ogoji.

Ifa iyawo                    Baba iyawo yoo difa ni aaro ojo igbeyawo lati mo ile oko naa yoo se

ri boya yoo san sowo somo.

Ojo igbeyawo Ale ni awon ebi ati ore iyawo yoo ba a palemo, won yoo sin iyawo lo

si ile oko pelu orin ati ijo titi yoo fi de enu ona oko re.

Ese iyawo                   Ni enu ona abawole won yoo fi omi we ese iyawo naa.

wiwe

 

Ibale                            Ti iyawo ko ba ti i mo okunrin kan ri, ti oko re ba a nile, oko yoo gbe

ekun agbe emu tabi ile isana kikun ranse si obi iyawo pelu owo ibale.

 

IGBELEWON

  1. Ki ni a n pe ni ifojusode ninu eto igbeyawo abinibi
  2. Se alaye ise alarena
  3. Kini ijohen tabi isihun tumo si?
  4. Kini iyato laarin itoro ati idana?

 

IGBEYAWO ODE ONI            DEETI……………………

 

AKORI ISE:                                                                                 

AKOONU:-

  • IGBEYAWO SOOSI
  • IGBEYAWO MOSOLASI
  • IGBEYAWO KOOTU

Lode oni, aye ti di amulumala. Orisirisii ona ni a n gba gbe iyawo.  A n gbe iyawo ni ile Olorun, a n gbe e ni kootu, a si n gbe ni mosalasi.  Igbeyawo soosi yii fese mule laarin awon onigbagbo, igbeyawo mosalasi si mule laarin awon musulumi.

15 Places to WIN $10,000
15 Places to WIN $10,000 Cash

 

Igbeyawo soosi ni eyi to maa n waye laarin awon elesin Kristeni ninu ile ijosin won, sugbon ki eto igbeyawo yii to waye ni won yoo ti maa kede eni to ba ri idi ti won ko le fi so oko ati iyawo naa papo ko tete wa so bi bee ko, ki eni be gbe enu re dake laelae.  Bi won ko ba tiri enikeni ko yoju ni won to le so awon mejeeji po.  Iru igbeyawo yii ko faye gba ju iyawo kan lo.

 

Igbeyawo mosolasi maa n waye laarin awon musulumi, eyi faye gba ju iyawo kan lo nitori won  ni “me” ni Olorun wi, ti agbara eniyan ba ti kaa.  Awon musulumi a maa fi omo se saara lai je pe onitohuni fi okan sii tele eyi ni pe ki won fun eniyan ni iyawo lairo tele (ki won fun eeyan ni iyawo ofe).  Eyi ni won naa n pe ni iyawo saara.

 

Orisii igbeyawo yii fese mule daadaa nile Yoruba nitori esin igbagbo ati Isilamu to fese mule lode oni.  Gbogbo ilana lati ibi itoro titi de idana maa n saba je eyi ti a n tele.

 

Awon loko laya miiran a ma n se igbeyawo alarede ti o je pe won a lo si olu ile-ise ijoba ibile tabi Kootu lati fowo si iwe ase lodo ijoba, won a si fi bee gba oruka arede.  Eleyii naa ko faye gba ju iyawo kan ati oko kan lo.Igbeyawo kootu ni a n pe e.

 

Ni aye ode oni ko si ohun to n je ekun iyawo mo, opolopo awon wundia iwoyi ni won ti daju, gbogbo won ni oju n kan lati lo ile oko.  Ko tile sohun to fe pawon

lekun nitori won ko ka ile oko si ohun babara.

 

APAPO IGBELEWON

  1. Salaye lori igbeyawo aye ode oni
  2. Ko iyato meta laarin igbeyawo aye ode oni ati aye atijo.
  3. Salaye lori ise ode

 

ISE ASETILEWA

  1. Awon………….. lo n se igbeyawo soosi (a) Musulumi (b) Igbagbo (d) Aborisa.
  2. Awon …………………………lo n se igbeyawo Mosolasi (a) musulumi (b) Igbagbo (d) Aborisa.
  3. Awon ……………………………lo maa fi omo se saara (a) Onigbagbo (b) Alarede (d) Musulumi
  4. Awon to maa n fe iyawo ju eyo kan lo lode oni ni (a) musulumi (b) soosi (d) kootu
  5. ‘titi iku yoo fi ya won’ inu inu irufe igbeyawo aye ode oni wo ni eyi je mo?. (a) musulumi (b) soosi (d) kootu.

 

APA KEJI

  1. Kini a n pe ni idana ninu eto igbeyawo nile Yoruba
  2. Kini ijohen, lati odo tani ijohen ti n wa?

 

See also

ORISII ONA TI A N GBA SOGE NILE YORUBA

ETO ISELU ODE-ONI

ETO ISELU ABINIBI ATI ODE ONI

ISEDA ORO-ORUKO

ORO – AYALO

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Get Fully Funded Scholarships

Free Visa, Free Scholarship Abroad

           Click Here to Apply

Acadlly