AKORI EKO: ATUNYEWO AWON EYA ARA IFO

Eya ara ifo ni awon orisirisii eya ara ti a maa n lo fun pipe iro ede”.

Abuda kan pataki ti o ya awa eniyan soto si awon eda yooku ni ebun oro-siso. Bi apeere, ti a ba so wi pe ‘Bawo ni nnkan’, awon eya ara kan wa ninu ara wa lati ori de ikun ti won jumo sise papo lati gba gbolohun ibeere yii jade. Awon eya ara bee ni a n pe ni eya-ara ifo. Aworan eye-ara ifo naa niyi:

 

 

AWORAN EYA-ARA IFO

 

 

 

ISORI EYA-ARA IFO

A le pin awon eya-ara ifo si eya meji. Awon ni:

(i) AWON EYA-ARA IFO AFOJURI: Awon wonyi ni eya-ara ifo ti a le fi oju ri nipa lilo digi tabi nnkan miiran. Awon naa ni:

Afase, Olele, Iho imu Ita gogongo, Ete oke, Ete isale, Eyin oke, Eyin isale, Iwaju ahon, Aarin ahon, Eyin ahon, Erigi, Ajaa enu.

(ii) AWON EYA-ARA IFO AIFOJURI: Awon wonyi ni awon eya-ara ifo ti won wa lati inu ikun si inu ofun ti a ko le fi oju ri rara. Awon ni:

Kaa ofun, inu gogongo, Tan-an-na ofun, komookun, Eka komookun, Edo-foro.

S/N EYA-ARA IFO APEJUWE ILO WON
1.

 

 

 

 

2.

Komookun

 

 

 

 

Edo foro

Edo-foro: Inu edo-foro ni eemi ti a n lo fun opo iro ede ti n tu jade sita. Eyi ni a n pe ni eemi edo-foro. Eran ara edo-foro maa n fe lati pese eemi amisinu tabi amisode fun oro siso.

 

Komookun ati Eka komookun: inu eka komookun mejeeji ati komookun ni eemi edo-foro n gba koja si inu gogongo ati enu.

3. Gogongo Ori komookun tente ni gogongo dabuu le ni ofun. A le ri ita gogongo ni ofun wa.
4. Tan-an-na ati Alafo Tan-an-na Inu gogongo ni tan-an-na wa. Inu alafo tan-an-na yii ni eemi edo-foro n gba jade si ona ofun.
5. Kaa Ofun, Kaa Enu ati Kaa Imu Oke tan-an-na ni awon kaa meteeta wonyi wa. Ona ikoja ni won je fun eemi yala eemi amisinu tabi amisode
6. Ahon Ahon je eya ara lo n kopa julo pipe iro ifo nitori pe o se e gbe si orisiirisii ipo. A le pin ahon si apa meta wonyi:

(i)                 Iwaju ahon

(ii)               Aarin ahon

(iii)             Eyin ahon

7. Ete A le paete po pekipeki; ete le fe seyin perese, tabi ki a su won po roboto. Idi niyi ti a fi n ni iro faweli perese tabi roboto.
8. Afase Ni enu, afasa le gbera soke tabi wale fun eemi lati ri aaye gba kaa imu tabi enu jade. Idi niyi ti a fi n ni iro aranmupe tabi iro airanmupe.
9. Eyin oke, Erigi, Aja-enu Afipe akanmole ni won. A n lo won po mo afipe asunsi lati pe iro. A n lo eyin-oke papo mo ete isale tabi iwaju ahon pelu arigi ati aja-enu.

 

AFIPE: Afipe ni eya ara yoowu ti o ba n kopa ninu iro pipe.

Afipe ni gbogbo awon eya ara-ifo ti won wa lati oke alafo tan-an-na ofun de enu ati imu. Aarin yii ni a n pe ni opona ajemohun.

A le pin awon eya-ara ifo ti eon je afipe si meji. Awon ni:

 • Afipe asunsi; ati
 • Afipe akanmole

AFIPE ASUNSI: Afipe asunsi ni awon eya ara isale enu ti won le gbera soke tabi sodo lati sun kan afipe akanmole ti a ba n pe iro. Awon ni: Olele, Ete isale, Iwaju ahon, Aarin ahon, Eyin ahon.

AFIPE AKANMOLE: Afipe akanmole ni awon eya ara oke enu ti won n duro gbari si oju kan ti a ba n pe iro. Awon ni: Ete oke, Ogiri ofun, Eyin oke, Afase, Aja-enu, Erigi, Kaa imu.

Awon eya-ara ifo miiran ti won wa ni opona ajemohun tun ni awon ise miiran ti won n se to yato si oro siso. Bi apeere, imu wa fun oorun gbigbo tabi mimi; eyin wa fun ounje wiwe, bee ni ahon wa fun tito nnkanwo. Opona ajemohun bere lati aarin oke alafo tan-an-na titi de enu ati imu.

 

 

AKORI EKO: AWON ORISA ATI BI A SE NBO WON

IPO OLODUMARE ATI ORISA

Awon Yoruba gba wi pe enikan wa ti o ni ogbon, agbara, to si ga ju gbogbo orisa ati eda aye lo. Eyi ni won n pe ni Olorun tabi ‘eni ti o ni orun’, ibi ti won gba gege bii ibugbe Re. Won mo, won si gba wi pe Olorun yii ni o tobi julo. Idi niyi ti won fi pe e ni Olodumare. Oniruru oruko ni won fun Olodumare lati fi igbagbo won han. Won ni “F’ija f’Olorun ja, f’owo leran”. Eyi fi Olodumare han bi onidajo ododo.

Alarina tabi alagbawi lasan ni awon orisa je laaarin Olodumare ati awon eda eniyan. Iranse Olodumare ni awon Yoruba ka won si. Olodumare ni o ran won wa si ile aye lati wa tun aye se. Idi niyi ti awon Yoruba se fi won si ipo pataki. Igbagbo Yoruba tun re e.

 • Awon orisa ni won le gbe ebe won de iwaju Olodumare. Won gbagbo pe nitori pe Olodumare ga ju fun awon lati maa sun mo nigba gbogbo. Bee ni awon orisa wonyi sun mo Olodumare niroti iranse re ni won. Bi a ba si fe gba nnkan lowo eniyan, eni ti o ba mo oju re ni a n toju ki o le je ise wa daadaa. Idi niyi ti awon Yoruba fi n toju awon oris, ti won fi n ko ile fun won.
 • Awon abami eda tabi emi buburu kan wa ti won le fi iku tabi aisan buburu je awon niya. Won n se ebo ati etutu lorisirisi lati petu fun abami eda ati lati wa oju rere won. Opolopo awon oke, odo, igi nla ati awon eni lile aye atijo, ti won ni eru lara ni won ti so di orisa akunlebo, bi apeere; Sango, Oya, Ogun ati bee bee lo. Igbagbo won ni pe awon emi buburu wonyi n gbe ori oke, abe apata, inu omi nlaati ara igi ti o ga pupo. Bee ni awon miiran n boa won abami eranko bii Onni, Ere tabi Ejo ati awonope ti o ba yo eka fun idi kan naa.

 

PATAKI ORISA LAWUJO YORUBA

Ti a ba n soro nipa orisa ile Yoruba, bi eni n soro nipa esin abalaye won ni. Awon orisa wonyi ti di ohun ti won n bo fun awon idi ti a ti menuba. Iwonyi ni pataki awon orisa yii ni awujo Yoruba.

 • Imuni mo orison eni: Awon agba ni “Odo to ba gbagbe orison gbigbe ni i gbe”. Awon orisa wonyi n je ki omo Yoruba mo esin idile won. Osagbemi, Efunkemi, Osuntokun, Abegunde je oruko idile oloosa. Olorisa Egungun ni won n so omo won ni Abegunde, awon Onifa ko je so omo won ni Osungbemi laelae. Awon orisa wonyi je ki a mo ona ti a to waye, eyi si n satona ihuwasi eni ni awujo.
 • Ipese aabo ati ipese ire gbogbo: Bi oro ba diju, ifa ni awon Yoruba maa n fi oro lo. O daju pe ko si nnkan ti a le fe dawole ni awujo Yoruba ti a ko ni bi Ifa. Bee naa ni a n bo egungun ni iranti awon ara orun fun idaabobo. Bee ni ko si ebo ti a le gbe leyin esu ki ebo naa fin.
 • Orisa gege bi amu eko iwa atata ati iwa-bi-Olorun: Awon orisa ile Yoruba ni eewo to n dari ihuwasi olusin. Obatala fe mimo mimo, ohun to funfun, ni iwa, ni ero ati ni ise. orisa Ogun ko fe iro. Idi niyi ti won fi n fi i buran i ile ejo. Orisa-Nla ko oro iwosi, ko ni ife si aso. O ko awon olusin re pe iyawo kan soso lo dara loode. O ni “A ko le gbe aarin oji eniyan k’a ma si wi”.
 • Orisa bi amu ilana akoso to to: Bi a ba wo itan iwase, bi Olodumare ti ni agbara to, to je pee da owo re ni gbogbo awon orisa, sibe o pin ise akoso fun olukuluku won. Orisa kookan lo n sakoso eka kookan ninu aye ti Olodumare da. Eyi je apeere rere fun awujo w ape ki a ma da wa gbogbo nnkan mo ori. Agbara pupo n seku pa ni. Oba nikan ko le da ilu se. awon ijoye ilu ni ojuse. Eto niyi yi a le mulo ninu eto iselu wa.
 • Ogun iyebiye: Ogun iyebiye ni an ri ko ni akoko odun awon orisa wonyi. Akoko naa maa n je asiko ajoyo, ijo ati orin kiko tabi ewi kike. Irufe orin yii ti di ogun iyebiye fun awon omo Yoruba. Awon orin bi Ijala are ode, Esa egungun, Sango pipe ti di ilumoka. Gege bi won n gbe awon ti Olodumare ba fi ke ni ile yii ati ni oke okun.
 • Amu imo fun awon onkowe: Awon onkowe n ri nnkan ko lori awon orisa fun ojo iwaju: awon onkowe itan tabi awon to n ko ewi n menuba oriki awon orisa ninu iwe won. Onkowe Yoruba ti ko bam o nipa awon orisa ile Yoruba ko le ko iwe to ye kooro ninu asa. Apeere iwe to samulo awon orisa ni Oba Koso ti Duro Ladipo ko, Obaluaye, ti Wale Ogunyemi ko. A ri i bi gbogbo awon orisa se dide pelu ija si ilu ti ko fi tiwon se. Iwe J.S. Sowande (Sobo Arobiodu) fi imo re to jinle ninu esin ati orisa Yoruba han ninu ewi yii fun awujo. O ni:

A ki i siwaju Olifa

A ki i siwaju Olorisa korisa

A ki i siwaju Olobatala reri ose;

A ki i siwaju Tisa liborin:

Bi a ba siwaju Tisa liborin

15 Places to WIN $10,000
15 Places to WIN $10,000 Cash

A ko maa gbo ki duuru kun.

 

ISE AMUTILEWA

 1. So igbagbo Yoruba nipa orisa
 2. Ko oriki awon orisa wonyi sile:
 1. So ipa pataki ti orisa ko laarin awon Yoruba
 2. So ipo Olodumare ati orisa bi igbagbo awon Yoruba.

 

OSE KEEJO

AKORI EKO: ATUNYEWO AWON IRO NINU EDE YORUBA

 

See also

AKORI EKO: ITESIWAJU AWON ORISA ILE YORUBA

AKORI EKO: ITESIWAJU EKO LORI ONA IBANISORO

OSE KERIN-IN

AARE BOOLU

AKORI EKO: AROKO ONI-SORO-N-GBESI

Leave a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Get Fully Funded Scholarships

Free Visa, Free Scholarship Abroad

           Click Here to Apply

Acadlly