Skip to content

AKORI EKO: ATUNYEWO AWON EYA GBOLOHUN

  Gbolohun ni oro tabi akojopo oro ti o ni itumo. Gbolohun le je ipede ti o ni itumo tabi ni ise ti o n se nibikibi ti o ba ti jeyo. Bakan naa a le pe gbolohun ni oro ti a le pin si spola oro-oruko ati apola ise.

  ISORI GBOLOHUN EDE YORUBA

  1. Gbolohun eleyo oro-ise tabi gbolohun abode
  2. Gbolohun alakanpo
  3. Gbolohun ibeere
  4. Gbolohun olopo oro-ise
  5. Gbolohun alaye
  6. Gbolohun ase
  7. Gbolohun iyisodi
  8. Gbolohun iba tabi kani
  9. Gbolohun akiyesi alatenumo
  10. Gbolohun asodoruko
  11. Gbolohun eleyo oro-ise tabi gbolohun abode: eyi ni ipede tabi afo ti o ni oro-ise kan ninu. Irufe gbolohun yii ni a tun mo si gbolohun kukuru. Bi apeere:
  12. Bisi sun
  13. Dayo gun igi

  iii. Fadekemi we gele

  1. Gbolohun alakanpo: eui ni ipede tabi gbolohun ti a lo oro asopo lati so gbolohun meji tabi ju bee lo po di eyo gbolohun kan soso. Bi apeere:

  Ile re tobi, iyara re kere = ile re tobi sugbon iyara re kere

  Temidayo lo si ibi ayeye naa

  Adeyemi lo si ibi ayeye naa

  = Temidayo ati Adeyemi lo si ibi ayeye naa

  1. Gbolohun ibeere: eyi ni awon gbolohun ti a fi n se ibeere. Awon wunren gbolohun ibeere ni, da, nko, tani, ati bee bee lo. Bi apeere:

  Adegoke da?

  Badejo nko?

  Ta ni o wa nibe?

  1. Gbolohun olopo oro-ise: gbolohun yii naa ni a mo si gbolohun onibo. Gbolohun yii maa n ju eyo oro-ise kan lo, oro-ise inu gbolohun yii le je meji tabi meta. Bi apeere:

  Mo jeun mo si yo

  Won n rin won n yan won si se oge

  Ise asetilewa: Ko apeere meji lori orisii gbolhun ti o mo

   

  ITESIWAJU ISE LORI ISORI GBOLOHUN

  1. Gbolohun alaye: eyi ni gbolhun ti a n lo lati so bi n kan se ri. Bi apeere:

  Won ti jewo bi oro ti se ri gan-an

  Iwe meweaa ni Bolude ka

  Ojo naa fere wu oku ole

  1. Gbolohun iba tabi kani: eyi ni gbolohun ti a fi n so bi nkan se ri ati idi ti o fi ri bee. Atoka re ni ‘bi’, ‘kaka’, ati ‘dipo’. Bi apeere:

  Bi mo ma lowo maa dara

  Kaka ki n jale, maa di eru

  Dipo ki n ra eran, maar a eba

  1. Gbolohun iyisodi: awon oro atoka gbolohun yii ni ‘ko’, ‘kii’, ‘ko’, ‘ma’. Bi apeere:

  Bisi ko wan i ana

  Femi o ri osere naa

  Akande kii wa si ipade dede

  Jegede kii je ewa

  1. Gbolohun akiyesi alatenumo: A maa n fi pe akiyesi si apa ibikan pato tabi koko kan ninu odidi gbolohun nipa lilo ‘ni’ ninu gbolohun abode ti a fe se atenumo. Bi apeere:

  Mo ra ile tuntun ni Abuja

  Rira ni mo ra ile

  Abuja ni mot i ra ile tuntun

  1. Gbolohun Ase: Eyi maa n waye nipo ipede ti o je kan-an nipa fun eniti a ba soro. A maa n lo o gege bi igba ti a fi n mu u je dandan fun eni naa. Bi apeere:

  Dake je!

  Dide duro ati bee bee lo

   

  Ise asetilewa

  Ko apeere kan-kan lori orisii gbolohun ti o se le ni ki o si ko meji lori gbolohun asodoruko.

   

  See also

  AKORI EKO: EWI AKOMOLEDE

  AKORI EKO: APOLA INU EDE YORUBA

  ASA ISINKU NI ILE YORUBA

  FONOLOJI EDE YORUBA

  AKOLE ISE: AROKO KIKO

  Leave a Reply

  Your email address will not be published. Required fields are marked *

  Get Fully Funded Scholarships

  Free Visa, Free Scholarship Abroad

             Click Here to Apply