Ede:- Aroko Asotan/Oniroyin (Narrative Essay)

Aroko atonisona asotan ni aroko ti a fi n so nipa isele ti a fi oju wari tabi awon ise ti a gbo lenu enikan

Ilana Fun Kiko Aroko Oniroyin

  1. Koko oro:- Eyi ni oro oro aroko
  2. Ero:- Akekoo gbodo ronu jinle daadaa ko to bere sii ko aroko yi
  • Eto:- Agbekale aroko oniroyin gbodo wa ni sisentele
  1. Ilo Ede:- Lara ilo ede ti akekoo gbodo se amulo ni akoto, ifamisi ori awon oro, owe, akanlo ede ati ona ede loririsiri.
  2. Igunle:- Eyi ni ipari aroko.  Nibe ni a oo ti soro soki nipa gbogbo nnkan ti a ti so ninu aroko yii.

Apeere ori aroko asotan

  1. Ere boolu alafesegba kan ti mo wo
  2. Ajeye are onilejile ti o koja ni ile iwe ni
  3. Ijanba oko ti o sele ni osodi ni ilu Eko
  4. Isomoloruko omo egbon mi obinrin
  5. Odun egungun kan to se oju ni
  6. odun eyo ti o koja ni ilu-eko

 

  Ilapa ero fu aroko asotan 

«  Isomoloruko omo egbon ni obiin »

  1. Ojo ati akoko ti ayele naa waye
  2. Imurasile saaju ojo naa
  3. Apejuwe bi eto isomoloruko naa ti lo
  4. Apejuwe awon eniyan ti o wa ni be ati orisirisi ebun
  5. Akoko jije mimu
  6. Ikadii:- Ero re lori isomoloruko naa

 

Igbelewon :-

  1. Kin ni aroko asotan
  2. Saleye ilana fun kiko aroko oniroyin
  • Ko ori oro ajemoroyin meta pere

 

Ise Asetilewa:-  yoruba Akayege iwe amusese fun ile eko sekondiri kekere iwe keji lati owo L. Orimogunje, K. Adebayo, F. Okiki(2012)  Oju Iwe ketalelogbon Eko ogun

 

ASA:-  Asa ogun jija (WAR/CONFLICT)

Eto isigun:-  Eyi ni ona ti Yoruba n gba ko ogun ba ilu, ileto tabi orile ede kan.

 

Awon igbese ti a gbodo gbe ki a to sigun ni wonyi:-

  1. Ifa dida ati irubo ajaye:- Yoruba kii sigun ki won ma difa.  Won gba pe ifa le so bi ogun ti awon fe ja yoo ti ri fun won.  Bi ifa ko ba fo ire, won yoo se etutu lati bori ogun
  2. Pipolongo laarin ilu:- Won yoo se eto ati ipolongo laarin ilu fun gbogbo ara ilu,. Asiko yii ni won you si ko omo ogun jo.  Awon bii ;
  3. Ipanle tabi janduku ilu
  4. Igara olosa
  5. Oloogun
  6. Ogboju ode
  7. Awon ti i se koriya fun awon jagun loju ogun bii, onilu, onirara, abbl.

Ete Ogun Jija

  1. Sise ota mo ile ki won ma le de ibi ti jije ati mimu won wa
  2. Dida oogun sinu omi tabi ounje awon ota
  3. Riro gbogbo ona ti o wo ilu ota ki won to ji
  4. Wiwo ilu lojiji ati kiko ota ni papamora
  5. Riran ise ohun si ilu ti a fe ko ki won si le tete tuba (bebe) ki won di eru tabi ki won ni awon n reti won

Ohun Elo Ogun

  1. Ijakadi
  2. Oko siso lu ara
  • Kanna kanna
  1. Ofa tita
  2. Kondo, kumo
  3. Ebo riru
  • Ada, ida
  • Ogede, ofo, aransi, gbetu-gbetu, owo
  1. Opakutele ti awon olori ogun maa n mu lowo – o maa n gba ni lowo iku ogun abbl.
  2. Ibon lorisirisi

 

Igbelewon:

  1. Salaye igbese meji ti a ni lati gbe bi a ba fe sigun wo ilu kan tabi ileto kan
  2. Daruko orisi eto ogun jija meta
  • Ko ohun elo ogun jija marun-un

 

Ise Asetilewa :-  ko ohun elo ogun jija marun un ti awon Ologun n se amulo lode oni

 

LITERSO:-  Ewi Alohun to je mo esin ibile (Oral Literature associated with traditional religions)

Esin ibile ni ona ti a n gba sin Olodumare (Olorun) ni ilana abalaye

Awon ewi olohun to je mo esin ibile

Ewi                 orisa

  1. Esa – pipe egungun
  2. Esu – pipe esu
  3. Saigo-pipe Sango
  4. Oya-pipe oya
  5. Ijala-sisun Ogun
  6. Iyere ifa Orunmila
  7. Orin arungbe Oro

Esu-pipe:-  Esu je okan lara awon orisa ile Yoruba ti o ni ogbon, igboya ati arekereke.  O je olopa fun olodumare ati eniyan.  Akoko odun esu ni won maa n pe esu.  Awon olusin re ni a n pe ni elesu.

Sango-pipe ;-  Itan fi ye w ape sango ro wa so de aye.  Oranfe ni ile re ni ilu-ile. Ife.  Akoko odun sango ni won maa n pe sango.  Awon olusin re ni a n pe ni Adosun sango.  Sango lo ni ara ati monamona

 

Igbelewon :

  1. Kinni esin ibile
  2. Ko ewi alohun ajemo esin ibile marun-un pelu orisa to ro mo okookan won

 

Ise Asetilewa :-  Gege bi akekoo ede Yoruba salaye iyato ati ijora ti o wa laaarin esin ibile ati esin atohun-rinwa(Christianity and Islamic religion)

 

See also

OSE KERIN (NARRATIVE ESSAY)

OSE KETA (DISCRIPTIVE ESSAY)

AKOLE ISE: EDE :AROSO ALAPEJUWE

Eto ise fun saa keji

ASA IGBEYAWO

Acadlly Playstore Brand logo 350 x 350
Acadlly