Akaye: Akaye ni kika ayoka kan ti o ni itumo ni ona ti o le gba yei yekeyeke.
Orisi ayoka ninu akaye
- Akaye oloro geere
- Akaye ewi
- Akaye oni isoro-n-gbesi
Igbese Ti A Ni Lati Tele Ki Ayoka Le Yeni Yekeyeke
- Kika ati mimo ohun ti ayoka naa da le lori
- Sise itupale ayoka ni finifinni
- Fifi imo ede, laakeye ati ifarabale ka ayoka naa sinu
- Dida awon koko-oro, owe ati akanlo ede inu ayoka naa mo
- Mimo orisiirisi ibeere ti o wa labe ayoka naa ati didahun awon ibeere ti o ni itumo
Apeere akaye onisoro-n-gbesi
Adufe: Ile iwe mi dara lopolopo
Ayinla :- Bi o ti le je pe owo re po
Asabi :- Obe to dun owo lo paa,, iwo ti o ba fe gba eko rere nipa ti eto eko o ni lati nawo
Adufe :- O se jara asabi, ayinla ko mo pe ile iwe Elias gbayi o gbeye kaari aye
Asabi :- Ko da iya mi ti seleri pe ni saa eto eko to n bo ile iwe re yi ni won yoo seto mi si
Ayinla :- Ah ! emi naa yoo royin fun awon obi mi
Adufe:- Ibi giga ni Olodumare yoo mu wa de o
Asabi:- Amin o
Ayinla:- Amin e po
Igbelewon:-
- Kin ni akaye
- Orisi ayoka meloo ni owa
- Ko igbese merin ti a ni lati tele ki ayoka to le ye ni yekeyeke
Ise Asetilewa :- Ibeere lati inu akaye onisoro-n-gbesi. Oke yii.
- Ore meloo ni o wa ninu ayoka yii? (a) mefa (b) meta (d) mewaa
- Oruko ile iwe adufe ni ________ (a) kings college (b) Opomuler citadel (d) Elias Secondary School
- Obe to dun, owo la pa a” jade lenu _________ (a) asabi (b) adufe (d) ayinla
- Iya ________ saleri lati pari ile-eko re (a) ayo (b) adufe (d) asabi
- Akole ti o ba ayoka yin mi ju ni (a) awon ore meta (b) ile iwe mi (d) obi mi
ASA :- ASA IKINI I
Asa ikini je ona ti awon yoruba n gba mo eni ti o ni eko ile. Bi omo ba ji ni owuro, dandan ni ki o dobale bi o je omokunrin, bi o ba si je obinrin o maa kunle lati ki awon obi re. Iwa Iteriba ni eyi je ni awujo wa. Iwa yi kii se fun obi ni kna, o wa fun gbogbo eni ti o ju ni lo.
Awon yoruba ni orisirisi ikini fun gbogbo akoko, ise, isele, ere abbl.
Ikini atigbadegba ati ise owo ni ile Yoruba
Orisi isele ati ise ikini Idahun
- Agbe aroko bodun de ase
- Ode arinpa ogun a gbe o
- Oni diri oju gboro ooya aya
- Babalawo aboruboye o awo orunmila a gbe o tabi aboye bo sise
- Ontaja aje a wo gba o aje yoo gbe o
- Oba ilu ki ade pe lori, irukere ni oba yoo fi dahun
Ki bat ape lese,
Igba odun, odun kan
- Oloye Ajegbo, ajeto, ajepe Ase
- Ontayo Mo ki ota, mo ki ope Ota n je, ope o gbodo fohun
- Akope Igba a roo Ogun a gbe o
- Awako Oko arefoo Ase o
- Ayeye igbeyawo Eyin iyawo ko ni ase, ire a kari
Meni o
- Ayeye isile Ile a tura o Ase, ire a kari
Igbelewon:-
- Salaye asa ikeru ri ile Yoruba
- Ba wo ni a se n ki awon wonyi ni ile Yoruba
- Eni to sese bimo
- Alaro
Ise Asetilewa:- Ko bi a se n ki awon wonyin ni ile Yoruba
(a) Amokoko (b) Ahunso (d) alagbede (e) apeja
LITERSO:- Kikea iwe itan apileko ere onise ti ijoba yan
See also
Ede:- Akaye oloro geere
Ede:- Akaye Oloro Geere wuuru
Ede:- Aroko Asotan/Oniroyin (Narrative Essay)
OSE KERIN (NARRATIVE ESSAY)
OSE KETA (DISCRIPTIVE ESSAY)